Ẹ́kísódù 28:1-43

  • Àwọn aṣọ àlùfáà (1-5)

  • Éfódì (6-14)

  • Aṣọ ìgbàyà (15-30)

    • Úrímù àti Túmímù (30)

  • Aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá (31-35)

  • Láwàní àti àwo dídán (36-39)

  • Àwọn aṣọ míì tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà (40-43)

28  “Kí o mú Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè di àlùfáà mi,+ Áárónì,+ pẹ̀lú Nádábù àti Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì,+ àwọn ọmọ Áárónì.+  Kí o ṣe aṣọ mímọ́ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kó lè ní ògo àti ẹwà.+  Kí o bá gbogbo àwọn tó mọṣẹ́* sọ̀rọ̀, àwọn tí mo ti fi ẹ̀mí ọgbọ́n kún inú wọn,+ kí wọ́n lè ṣe aṣọ Áárónì láti sọ ọ́ di mímọ́, kó lè di àlùfáà mi.  “Àwọn aṣọ tí wọ́n á ṣe nìyí: aṣọ ìgbàyà,+ éfódì,+ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá,+ aṣọ tó ní bátànì igun mẹ́rin, láwàní+ àti ọ̀já;+ kí wọ́n ṣe àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó lè di àlùfáà mi.  Àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ náà yóò lo wúrà náà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa.  “Kí wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa láti fi ṣe éfódì, kí wọ́n sì kóṣẹ́ sí i.+  Kí ó ní aṣọ méjì ní èjìká tó máa so pọ̀ mọ́ etí méjèèjì éfódì náà.  Ní ti àmùrè* tí wọ́n hun,+ èyí tó wà lára éfódì náà láti dì í mú kó lè dúró dáadáa, ohun kan náà ni kí wọ́n fi ṣe é, kí wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.  “Kí o mú òkúta ónísì méjì,+ kí o sì fín orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára wọn,+ 10  orúkọ mẹ́fà lára òkúta kan, orúkọ mẹ́fà tó ṣẹ́ kù lára òkúta kejì, bí wọ́n ṣe bí wọn tẹ̀ léra. 11  Kí oníṣẹ́ ọnà òkúta fín orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára òkúta méjèèjì bí ìgbà tó ń fín èdìdì.+ Kí o wá fi wúrà tẹ́lẹ̀ wọn. 12  Kí o fi òkúta méjèèjì sórí àwọn aṣọ èjìká éfódì náà, kó lè jẹ́ òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí orúkọ wọn sì máa wà ní èjìká Áárónì méjèèjì, kó lè jẹ́ ohun ìrántí tó bá wá síwájú Jèhófà. 13  Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀, 14  kí o sì fi ògidì wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n méjì, kí o lọ́ ọ pọ̀ bí okùn,+ kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n tó dà bí okùn náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà.+ 15  “Kí o mú kí ẹni tó ń kó iṣẹ́ sí aṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà ìdájọ́.+ Kó ṣe é bí éfódì, kí ó lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa láti fi ṣe é.+ 16  Kí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, kó jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan* ní gígùn àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan ní fífẹ̀. 17  Kí o to àwọn òkúta sórí rẹ̀, kí o to òkúta náà ní ìpele mẹ́rin. Kí ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ rúbì, tópásì àti émírádì. 18  Kí ìpele kejì jẹ́ tọ́kọ́wásì, sàfáyà àti jásípérì. 19  Kí ìpele kẹta jẹ́ òkúta léṣémù,* ágétì àti ámétísì. 20  Kí ìpele kẹrin jẹ́ kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Kí o lẹ̀ wọ́n mọ́ ìtẹ́lẹ̀ tí o fi wúrà ṣe. 21  Àwọn òkúta náà yóò dúró fún orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (12). Kí o fín orúkọ sára òkúta kọ̀ọ̀kan bí èdìdì, kí orúkọ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà. 22  “Kí o ṣe ẹ̀wọ̀n tó lọ́ pọ̀ sára aṣọ ìgbàyà náà, bí okùn tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe.+ 23  Kí o ṣe òrùka wúrà méjì sára aṣọ ìgbàyà náà, kí o sì fi òrùka méjèèjì sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà. 24  Kí o ki okùn oníwúrà méjèèjì bọnú àwọn òrùka méjì tó wà ní igun aṣọ ìgbàyà náà. 25  Kí o wá ki etí okùn méjèèjì bọnú ìtẹ́lẹ̀ méjèèjì náà, kí o sì so wọ́n mọ́ àwọn aṣọ èjìká éfódì náà níwájú. 26  Kí o ṣe òrùka wúrà méjì, kí o sì fi wọ́n sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà ní inú, kó dojú kọ éfódì náà.+ 27  Kí o tún ṣe òrùka wúrà méjì síwájú éfódì náà, nísàlẹ̀ aṣọ èjìká méjèèjì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tó ti so pọ̀, lókè àmùrè* éfódì náà tí wọ́n hun.+ 28  Kí o fi okùn aláwọ̀ búlúù di aṣọ ìgbàyà náà mú, kí o fi okùn náà so àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì. Èyí máa mú kí aṣọ ìgbàyà náà dúró lórí éfódì náà, lókè àmùrè* éfódì tí wọ́n hun. 29  “Kí orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì máa wà lára aṣọ ìgbàyà ìdájọ́ tó wà ní àyà Áárónì nígbà tó bá wá sínú Ibi Mímọ́, kó lè jẹ́ ohun ìrántí níwájú Jèhófà nígbà gbogbo. 30  Kí o fi Úrímù àti Túmímù*+ sínú aṣọ ìgbàyà ìdájọ́ náà, kí wọ́n sì máa wà ní àyà Áárónì nígbà tó bá wá síwájú Jèhófà, kí Áárónì máa gbé ohun tí wọ́n fi ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí àyà rẹ̀ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo. 31  “Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ni kí o lò látòkè délẹ̀ láti fi ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá sí éfódì náà.+ 32  Kí o yọ ọrùn* sí aṣọ náà, ní àárín. Kí ẹni tó ń hun aṣọ ṣe ìgbátí sí ọrùn rẹ̀ yí ká. Kí o ṣe ọrùn aṣọ náà bíi ti ẹ̀wù irin, kó má bàa ya. 33  Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ṣe pómégíránétì sí etí aṣọ náà yí ká, kí o sì fi àwọn agogo wúrà sáàárín wọn. 34  Kí o to agogo wúrà kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan, agogo wúrà kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà. 35  Kí Áárónì wọ̀ ọ́ kó lè máa fi ṣiṣẹ́, kí àwọn ohun tó wà lára aṣọ náà sì máa dún nígbà tó bá ń wọ inú ibi mímọ́ níwájú Jèhófà àti nígbà tó bá ń jáde, kó má bàa kú.+ 36  “Kí o fi ògidì wúrà ṣe irin pẹlẹbẹ tó ń dán, kí o sì fín ọ̀rọ̀ yìí sára rẹ̀ bí ẹni fín èdìdì, pé: ‘Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.’+ 37  Kí o fi okùn aláwọ̀ búlúù dè é mọ́ ara láwàní;+ kó máa wà níwájú láwàní náà. 38  Yóò wà ní iwájú orí Áárónì, kí Áárónì sì máa ru ẹ̀bi ẹni tó bá ṣe ohun tí kò tọ́ sí àwọn ohun mímọ́,+ èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sí mímọ́ nígbà tí wọ́n fi ṣe ẹ̀bùn mímọ́. Kò gbọ́dọ̀ kúrò níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè rí ojú rere Jèhófà. 39  “Kí o fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa hun aṣọ tó ní bátànì igun mẹ́rin, kí o sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe láwàní, kí o sì hun ọ̀já.+ 40  “Kí o tún ṣe aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ọ̀já fún àwọn ọmọ Áárónì+ pẹ̀lú aṣọ tí wọ́n máa wé sórí, kí wọ́n lè ní ògo àti ẹwà.+ 41  Kí o wọ aṣọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí o fòróró yàn wọ́n,+ kí o fiṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́,*+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́, wọ́n á sì di àlùfáà mi. 42  Kí o tún fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ṣòkòtò péńpé* fún wọn kó lè bo ìhòòhò wọn.+ Kó gùn láti ìbàdí dé itan. 43  Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí wọ́n bá wá sínú àgọ́ ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n wá síbi pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ nínú ibi mímọ́, kí wọ́n má bàa jẹ̀bi, kí wọ́n sì kú. Òun àti àwọn ọmọ* rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa pa àṣẹ yìí mọ́ títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). Wo Àfikún B14.
Òkúta iyebíye kan tí a ò mọ bó ṣe rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òkúta áńbérì, háyásíǹtì, ópálì tàbí tọ́málínì.
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “ibi tó máa ki orí sí.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ wọn.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “èso.”