Ẹ́kísódù 19:1-25

  • Ní Òkè Sínáì (1-25)

    • Ísírẹ́lì yóò di ìjọba àwọn àlùfáà (5, 6)

    • Ó sọ àwọn èèyàn di mímọ́ láti pàdé Ọlọ́run (14, 15)

19  Ní ọjọ́ tó pé oṣù mẹ́ta tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n dé aginjù Sínáì.  Wọ́n ṣí kúrò ní Réfídímù,+ wọ́n dé aginjù Sínáì, wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù náà. Ísírẹ́lì pàgọ́ síbẹ̀ níwájú òkè náà.+  Mósè wá gòkè lọ bá Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà sì pè é láti òkè náà+ pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún ilé Jékọ́bù àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí,  ‘Ẹ ti fojú ara yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì,+ kí n lè fi àwọn ìyẹ́ idì gbé yín wá sọ́dọ̀ ara mi.+  Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn mi délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, ó dájú pé ẹ ó di ohun ìní mi pàtàkì* nínú gbogbo èèyàn,+ torí gbogbo ayé jẹ́ tèmi.+  Ẹ ó di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’+ Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn.”  Mósè wá pe àwọn àgbààgbà láàárín àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn nípa gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tí Jèhófà pa láṣẹ fún un.+  Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn náà fohùn ṣọ̀kan, wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè mú èsì àwọn èèyàn náà tọ Jèhófà lọ.  Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Màá wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìkùukùu* tó ṣú dùdù, kí àwọn èèyàn náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ máa gba ìwọ náà gbọ́.” Lẹ́yìn náà, Mósè mú èsì àwọn èèyàn náà tọ Jèhófà lọ. 10  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Lọ bá àwọn èèyàn náà, kí o sọ wọ́n di mímọ́ lónìí àti lọ́la, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 11  Kí wọ́n múra sílẹ̀ de ọjọ́ kẹta, torí pé ní ọjọ́ kẹta, Jèhófà yóò sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì níṣojú gbogbo àwọn èèyàn náà. 12  Kí o pa ààlà yí òkè náà ká fún àwọn èèyàn náà, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má gun òkè náà, ẹ má sì fara kan ààlà rẹ̀. Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkè náà yóò kú. 13  Ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ẹni náà, ṣe ni kí ẹ sọ ọ́ lókùúta tàbí kí ẹ gún un ní àgúnyọ.* Ẹ ò ní dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, yálà ẹranko ni tàbí èèyàn.’+ Àmọ́ tí ìró ìwo àgbò bá ti dún,+ kí àwọn èèyàn náà wá sí òkè náà.” 14  Lẹ́yìn náà, Mósè sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè, ó sì lọ bá àwọn èèyàn náà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.+ 15  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ múra sílẹ̀ de ọjọ́ kẹta. Ẹ má ṣe ní ìbálòpọ̀.”* 16  Ní àárọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá sán, mànàmáná kọ. Àwọsánmà ṣú+ bo orí òkè, ìró ìwo sì dún sókè gan-an, ẹ̀rù wá ń ba gbogbo àwọn tó wà nínú àgọ́.+ 17  Mósè sì mú àwọn èèyàn náà kúrò nínú àgọ́ láti pàdé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n dúró ní ìsàlẹ̀ òkè náà. 18  Èéfín ń rú ní gbogbo Òkè Sínáì, torí Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀ nínú iná;+ èéfín rẹ̀ sì ń lọ sókè bíi ti iná ìléru, gbogbo òkè náà sì ń mì tìtì.+ 19  Bí ìró ìwo náà ṣe túbọ̀ ń dún kíkankíkan, Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ sì dá a lóhùn.* 20  Jèhófà wá sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì. Lẹ́yìn náà, Jèhófà pe Mósè wá sí orí òkè náà, Mósè sì gòkè lọ.+ 21  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ̀ kalẹ̀, kí o lọ kìlọ̀ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n má fi dandan wá ọ̀nà láti wo Jèhófà, kí ọ̀pọ̀ nínú wọn má bàa pa run. 22  Jẹ́ kí àwọn àlùfáà tó ń wá síwájú Jèhófà déédéé sọ ara wọn di mímọ́, kí Jèhófà má bàa pa* wọ́n.”+ 23  Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Àwọn èèyàn náà ò lè wá sórí Òkè Sínáì, torí o ti kìlọ̀ fún wa tẹ́lẹ̀ pé, ‘Pa ààlà yí òkè náà ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’”+ 24  Àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì pa dà wá sókè, ìwọ àti Áárónì, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà fipá gòkè wá sọ́dọ̀ Jèhófà, kó má bàa pa wọ́n.”+ 25  Mósè wá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó ṣeyebíye.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pẹ̀lú ọfà.
Ní Héb., “Ẹ má ṣe sún mọ́ obìnrin.”
Ní Héb., “ohùn Ọlọ́run tòótọ́ sì dá a lóhùn.”
Ní Héb., “kọ lù.”