Ẹ́kísódù 17:1-16

  • Wọ́n ráhùn pé wọn ò rí omi mu ní Hórébù (1-4)

  • Omi jáde látinú àpáta (5-7)

  • Àwọn ọmọ Ámálékì gbógun ja Ísírẹ́lì, àmọ́ wọn ò borí (8-16)

17  Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní aginjù Sínì+ láti ibì kan sí ibòmíì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ,+ wọ́n sì pàgọ́ sí Réfídímù.+ Àmọ́ àwọn èèyàn náà ò rí omi mu.  Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá Mósè jà,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Fún wa lómi mu.” Àmọ́ Mósè bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá mi jà? Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán Jèhófà wò?”+  Síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ àwọn èèyàn náà gan-an níbẹ̀, wọ́n sì ń kùn sí Mósè ṣáá,+ wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì kí o lè fi òùngbẹ pa àwa àti àwọn ọmọ wa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”  Níkẹyìn, Mósè ké pe Jèhófà, ó ní: “Kí ni màá ti ṣe àwọn èèyàn yìí sí? Wọn ò ní pẹ́ sọ mí lókùúta!”  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí o sì mú lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì dání pẹ̀lú ọ̀pá rẹ tí o fi lu odò Náílì.+ Mú un dání kí o sì máa lọ.  Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ lórí àpáta tó wà ní Hórébù. Kí o lu àpáta náà, omi yóò jáde látinú rẹ̀, àwọn èèyàn náà á sì mu ún.”+ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.  Ó wá pe ibẹ̀ ní Másà*+ àti Mẹ́ríbà,*+ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá a jà àti pé wọ́n dán Jèhófà wò,+ wọ́n ní: “Ṣé Jèhófà wà láàárín wa àbí kò sí?”  Àwọn ọmọ Ámálékì+ wá bá Ísírẹ́lì jà ní Réfídímù.+  Ni Mósè bá sọ fún Jóṣúà+ pé: “Bá wa yan àwọn ọkùnrin, kí o sì lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Ní ọ̀la, màá dúró sórí òkè, màá sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání.” 10  Jóṣúà ṣe ohun tí Mósè sọ fún un,+ ó sì bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Mósè, Áárónì àti Húrì  + wá gun òkè náà lọ. 11  Tí ọwọ́ Mósè bá wà lókè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń borí, àmọ́ tó bá ti lè gbé ọwọ́ rẹ̀ wálẹ̀, àwọn ọmọ Ámálékì á máa borí. 12  Nígbà tí ọwọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ro Mósè, wọ́n gbé òkúta kan sábẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé e. Áárónì àti Húrì wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ Mósè lọ́tùn-ún àti lósì, wọ́n bá a gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ọwọ́ rẹ̀ sì dúró gbọn-in títí oòrùn fi wọ̀. 13  Bí Jóṣúà ṣe fi idà ṣẹ́gun Ámálékì àti àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn.+ 14  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé fún ìrántí, kí o sì tún un sọ fún Jóṣúà pé, ‘Màá mú kí wọ́n gbàgbé Ámálékì pátápátá lábẹ́ ọ̀run.’”+ 15  Mósè mọ pẹpẹ kan, ó sì sọ ọ́ ní Jèhófà-nisì,* 16  ó ní: “Torí ó gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Jáà,+ Jèhófà yóò máa gbógun ja Ámálékì láti ìran dé ìran.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Àdánwò.”
Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Òpó Àmì Mi.”