Àwọn Onídàájọ́ 19:1-30
-
Ìṣekúṣe tí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ṣe ní Gíbíà (1-30)
19 Nígbà yẹn, tí kò sí ọba ní Ísírẹ́lì,+ ọmọ Léfì kan tó ń gbé apá ibi tó jìnnà ní agbègbè olókè Éfúrémù+ lákòókò yẹn fẹ́ wáhàrì* kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà.
2 Àmọ́ wáhàrì rẹ̀ dalẹ̀ rẹ̀, ó sì fi ọkùnrin náà sílẹ̀, ó wá pa dà sí ilé bàbá rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà. Oṣù mẹ́rin ló fi wà níbẹ̀.
3 Ọkọ rẹ̀ wá lọ bá a kó lè rọ̀ ọ́ pé kó pa dà wá; ó mú ìránṣẹ́kùnrin rẹ̀ àtàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ dání. Obìnrin náà wá mú un wá sínú ilé bàbá rẹ̀. Nígbà tí bàbá rẹ̀ rí ọkùnrin náà, inú rẹ̀ dùn pé òun rí i.
4 Bàbá ìyàwó rẹ̀, ìyẹn bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà wá mú kó dúró ti òun fún ọjọ́ mẹ́ta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, ó sì ń sun ibẹ̀ mọ́jú.
5 Nígbà tí wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kẹrin kí wọ́n lè máa lọ, bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún ọkọ ọmọ rẹ̀ pé: “Jẹun kí o lè lókun,* kí o tó máa lọ.”
6 Torí náà, wọ́n jókòó, àwọn méjèèjì jọ jẹun, wọ́n sì mu; lẹ́yìn náà, bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún ọkùnrin náà pé: “Jọ̀ọ́, sùn síbí mọ́jú, kí o sì gbádùn ara rẹ.”*
7 Nígbà tí ọkùnrin náà dìde kó lè máa lọ, bàbá ìyàwó rẹ̀ ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá, ló bá tún sun ibẹ̀ mọ́jú.
8 Nígbà tó dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ karùn-ún kó lè máa lọ, bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹun kí o lè lókun.”* Wọ́n wá ń fi nǹkan falẹ̀ títí ọjọ́ fi lọ, àwọn méjèèjì ò kúrò nídìí oúnjẹ.
9 Nígbà tí ọkùnrin náà dìde kí òun àti wáhàrì rẹ̀ pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ lè máa lọ, bàbá ìyàwó rẹ̀, ìyẹn bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà, sọ fún un pé: “Wò ó! Ilẹ̀ ò ní pẹ́ ṣú báyìí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sùn síbí mọ́jú. Ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣú. Sùn síbí mọ́jú, kí o sì gbádùn ara rẹ. Tó bá di ọ̀la, ẹ lè dìde ní àárọ̀ kùtù kí ẹ máa lọ, kí o sì pa dà sí ilé* rẹ.”
10 Àmọ́ ọkùnrin náà ò tún fẹ́ sun ibẹ̀ mọ́jú, torí náà, ó gbéra, ó sì rìnrìn àjò títí dé Jébúsì, ìyẹn Jerúsálẹ́mù.+ Ó mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí wọ́n de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́* dání pẹ̀lú wáhàrì rẹ̀ àti ìránṣẹ́ rẹ̀.
11 Nígbà tí wọ́n dé tòsí Jébúsì, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ. Ìránṣẹ́ náà wá bi ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ṣé ká dúró ní ìlú àwọn ará Jébúsì yìí ká sì sun ibẹ̀ mọ́jú?”
12 Àmọ́ ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé: “Kò yẹ ká dúró ní ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Ká máa lọ títí a fi máa dé Gíbíà.”+
13 Ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Máa bọ̀, jẹ́ ká gbìyànjú láti dé ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà; a máa sun Gíbíà tàbí Rámà+ mọ́jú.”
14 Wọ́n wá ń bá ìrìn àjò wọn lọ, oòrùn sì ti ń wọ̀ nígbà tí wọ́n ń sún mọ́ Gíbíà, tó jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì.
15 Wọ́n wá dúró níbẹ̀, wọ́n sì wọlé lọ sí Gíbíà kí wọ́n lè sun ibẹ̀ mọ́jú. Lẹ́yìn tí wọ́n wọlé, wọ́n jókòó sí ojúde ìlú náà, àmọ́ kò sí ẹni tó gbà wọ́n sílé kí wọ́n lè sun ibẹ̀ mọ́jú.+
16 Nígbà tó yá, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, bàbá arúgbó kan ń ti oko bọ̀ níbi tó ti lọ ṣiṣẹ́. Agbègbè olókè Éfúrémù+ ló ti wá, ó sì ń gbé fúngbà díẹ̀ ní Gíbíà; àmọ́ ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni àwọn tó ń gbé ìlú náà.
17 Nígbà tó wòkè tó sì rí arìnrìn-àjò náà ní ojúde ìlú, bàbá arúgbó náà bi í pé: “Ibo lo ti ń bọ̀, ibo lo sì ń lọ?”
18 Ó fèsì pé: “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà la ti ń bọ̀, a sì ń lọ síbi tó jìnnà ní agbègbè olókè Éfúrémù, níbi tí mo ti wá. Mo lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà,+ mo sì ń lọ sí ilé Jèhófà,* àmọ́ ẹnì kankan ò gbà mí sílé.
19 A ní pòròpórò àti oúnjẹ ẹran tó máa tó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ wa, a sì ní oúnjẹ+ àti wáìnì tí èmi, obìnrin náà àti ìránṣẹ́ wa máa jẹ. A ò ṣaláìní ohunkóhun.”
20 Àmọ́ bàbá arúgbó náà sọ pé: “Àlàáfíà fún ọ! Jẹ́ kí n pèsè ohunkóhun tí o bá nílò. Ṣáà má sun ojúde ìlú mọ́jú.”
21 Ó wá mú un wá sínú ilé rẹ̀, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní oúnjẹ.* Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
22 Bí wọ́n ṣe ń gbádùn ara wọn, àwọn ọkùnrin kan tí kò ní láárí nínú ìlú yí ilé náà ká, wọ́n sì ń gbá ilẹ̀kùn, wọ́n ń sọ fún bàbá arúgbó tó ni ilé náà pé: “Mú ọkùnrin tó wá sínú ilé rẹ jáde, ká lè bá a lò pọ̀.”+
23 Ni onílé bá jáde lọ sọ fún wọn pé: “Rárá o, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ má hùwà burúkú. Ẹ jọ̀ọ́, àlejò ni ọkùnrin tó wà nínú ilé mi yìí. Ẹ má hùwà tó ń tini lójú yìí.
24 Ọmọbìnrin mi tí kò tíì mọ ọkùnrin àti wáhàrì ọkùnrin náà nìyí. Ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde, kí ẹ sì bá wọn lò pọ̀ tó bá jẹ́ ohun tí ẹ fẹ́ nìyẹn.*+ Àmọ́ ẹ má hùwà tó ń tini lójú yìí sí ọkùnrin yìí.”
25 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò dá a lóhùn. Torí náà, ọkùnrin náà mú wáhàrì rẹ̀+ jáde fún wọn. Wọ́n fipá bá a lò pọ̀, wọ́n sì ṣe obìnrin náà ṣúkaṣùka ní gbogbo òru títí di àárọ̀. Wọ́n wá ní kó máa lọ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀.
26 Obìnrin náà dé ní àárọ̀ kùtù, ó sì ṣubú sí ẹnu ọ̀nà ilé ọkùnrin tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó dùbúlẹ̀ síbẹ̀ títí ilẹ̀ fi mọ́.
27 Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ dìde ní àárọ̀, tó ṣí ilẹ̀kùn ilé náà kó lè máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó rí obìnrin náà, wáhàrì rẹ̀, tó dùbúlẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ síbi àbáwọlé.
28 Ó wá sọ fún un pé: “Dìde, jẹ́ ká lọ.” Àmọ́ kò dáhùn. Ọkùnrin náà wá gbé e sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì forí lé ilé rẹ̀.
29 Nígbà tó dé ilé rẹ̀, ó mú ọ̀bẹ ìpẹran, ó wá mú wáhàrì rẹ̀, ó sì gé e sí ọ̀nà méjìlá (12), ó wá fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì.
30 Gbogbo àwọn tó rí i sọ pé: “Irú èyí ò ṣẹlẹ̀ rí, a ò sì rí irú rẹ̀ rí látọjọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí dòní. Ẹ rò ó wò,* ẹ gbà wá nímọ̀ràn,+ kí ẹ sì sọ ohun tí a máa ṣe fún wa.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
^ Tàbí “kí o lè gbé ọkàn rẹ ró.”
^ Tàbí “kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ jẹ̀gbádùn.”
^ Tàbí “kí o lè gbé ọkàn rẹ ró.”
^ Ní Héb., “àgọ́.”
^ Tàbí “tí wọ́n dì ní gàárì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ilé Jèhófà ni mo sì ti ń sìn.”
^ Tàbí “oúnjẹ ẹran tí wọ́n pò mọ́ra.”
^ Tàbí “bá wọn lò pọ̀ kí ẹ sì ṣe ohun tó bá dáa lójú yín.”
^ Tàbí “Ẹ fi ọkàn yín sí i.”