Sekaráyà 2:1-13

2  Mo sì tẹ̀ síwájú láti gbé ojú mi sókè, mo sì rí i; sì wò ó! ọkùnrin kan wà, ìjàrá tí a fi ń wọn nǹkan+ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.  Nítorí náà, mo wí pé: “Ibo ni ìwọ ń lọ?” Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún mi pé: “Láti wọn Jerúsálẹ́mù, láti mọ ohun tí ìbú rẹ̀ jẹ́ àti ohun tí gígùn rẹ̀ jẹ́.”+  Sì wò ó! áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ ń jáde lọ, áńgẹ́lì mìíràn sì ń jáde lọ láti pàdé rẹ̀.  Nígbà náà ni ó wí fún un pé: “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́kùnrin tí ó wà níbẹ̀ yẹn, pé, ‘“Bí ìlẹ̀ ìletò gbalasa ni a óò gbé nínú Jerúsálẹ́mù,+ nítorí ògìdìgbó ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀ tí ó wà nínú rẹ̀.+  Èmi fúnra mi yóò sì jẹ́ ògiri iná fún un yí ká,+ ògo sì ni èmi yóò jẹ́ ní àárín rẹ̀.”’” ni àsọjáde Jèhófà.+  “Héè! Héè! Ẹ sá lọ, nígbà náà, kúrò ní ilẹ̀ àríwá,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí pé ìhà ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run ni mo fọ́n yín káàkiri sí,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Héè, Síónì!+ Sá àsálà, ìwọ tí ń gbé pẹ̀lú ọmọbìnrin Bábílónì.+  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ní títẹ̀ lé ògo,+ ó ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń fi yín ṣe ìjẹ;+ nítorí pé ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín+ ń fọwọ́ kan ẹyinjú+ mi.  Nítorí kíyè sí i, èmi yóò ju ọwọ́ mi lòdì sí wọn,+ wọn yóò sì di ohun ìfiṣèjẹ fún àwọn ẹrú wọn.’+ Ẹ ó sì mọ̀ dájúdájú pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ni ó rán mi.+ 10  “Kígbe rara, kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+ nítorí kíyè sí i, mo ń bọ̀,+ dájúdájú, èmi yóò sì máa gbé ní àárín rẹ,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 11  “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò sì dara pọ̀ mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà dájúdájú,+ ní ti tòótọ́, wọn yóò sì di ènìyàn mi;+ dájúdájú, èmi yóò sì máa gbé ní àárín rẹ.” Ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ni ó rán mi sí ọ.+ 12  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì gba Júdà bí ìpín rẹ̀ lórí ilẹ̀ mímọ́,+ síbẹ̀, yóò sì yan Jerúsálẹ́mù.+ 13  Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, gbogbo ẹran ara, níwájú Jèhófà,+ nítorí ó ti ru ara rẹ̀+ dìde láti ibùgbé rẹ̀ mímọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé