Sekaráyà 13:1-9
13 “Ní ọjọ́ yẹn,+ kànga+ kan yóò wà tí a ṣí fún ilé Dáfídì àti fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù fún ẹ̀ṣẹ̀+ àti fún ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn.+
2 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, “pé èmi yóò ké orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà,+ a kì yóò sì rántí wọn mọ́; àti àwọn wòlíì+ àti ẹ̀mí ìwà àìmọ́ ni èmi yóò mú kí ó kúrò ní ilẹ̀ náà pẹ̀lú.+
3 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ọkùnrin kan bá tún sọ tẹ́lẹ̀, baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀, àwọn tí ó bí i, yóò sọ fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ kì yóò wà láàyè, nítorí pé èké ni ìwọ sọ ní orúkọ Jèhófà.’ Baba rẹ̀ àti ìyà rẹ̀, àwọn tí ó bí i, yóò sì gún un ní àgúnyọ nítorí ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.+
4 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, ojú yóò ti àwọn wòlíì,+ olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọ tẹ́lẹ̀; wọn kì yóò sì wọ ẹ̀wù oyè ti a fi irun+ ṣe fún ète títannijẹ.
5 Òun yóò sì wí dájúdájú pé, ‘Èmi kì í ṣe wòlíì. Ọkùnrin tí ń ro ilẹ̀ ni mí, nítorí pé ará ayé ni ó gbà mí síṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’
6 Ẹnì kan yóò sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ wo ni ìwọ̀nyí lára rẹ láàárín ọwọ́ rẹ?’ Òun yóò sì wí pé, ‘Ìwọ̀nyí ni a dá sí mi lára ní ilé àwọn olùfẹ́ mi lọ́nà gbígbóná janjan.’”
7 “Ìwọ idà, jí sí olùṣọ́ àgùntàn mi,+ àní sí abarapá ọkùnrin tí ó jẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. “Kọlu olùṣọ́ àgùntàn,+ kí agbo ẹran sì tú ká;+ dájúdájú, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí àwọn tí kò jámọ́ pàtàkì.”+
8 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ náà,” ni àsọjáde Jèhófà, “pé apá méjì nínú rẹ̀ ni a óò ké kúrò tí yóò sì gbẹ́mìí mì;+ àti ní ti apá kẹta, yóò ṣẹ́ kù nínú rẹ̀.+
9 Dájúdájú, èmi yóò sì mú apá kẹta lá iná kọjá;+ ní ti tòótọ́, èmi yóò sì yọ́ wọn mọ́ bí ẹni yọ́ fàdákà mọ́,+ èmi yóò sì yẹ̀ wọ́n wò bí ẹni yẹ wúrà wò.+ Òun, ní tirẹ̀, yóò ké pe orúkọ mi, àti èmi, ní tèmi, yóò dá a lóhùn.+ Èmi yóò wí pé, ‘Ènìyàn mi ni,’+ àti òun, ẹ̀wẹ̀ yóò wí pé, ‘Jèhófà ni Ọlọ́run mi.’”+

