Sáàmù 99:1-9

99  Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.+ Kí ṣìbáṣìbo bá àwọn ènìyàn.+Ó jókòó lórí àwọn kérúbù.+ Kí ilẹ̀ ayé gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.+  2  Jèhófà tóbi ní Síónì,+Ó sì ga ju gbogbo ènìyàn lọ.+  3  Kí wọ́n gbé orúkọ rẹ lárugẹ.+Títóbi àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni, mímọ́ ni.+  4  Àti pé nínú okun ọba, òun nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́.+Ìwọ tìkára rẹ ti fìdí ìdúróṣánṣán múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+Ìdájọ́ àti òdodo ni ìwọ tìkára rẹ ti fi múlẹ̀ ní Jékọ́bù.+  5  Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+ kí ẹ sì tẹrí ba níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;+Ẹni mímọ́ ni.+  6  Mósè àti Áárónì wà lára àwọn àlùfáà rẹ̀,+Sámúẹ́lì sì wà lára àwọn tí ń ké pe orúkọ rẹ̀.+Wọ́n ń pe Jèhófà, òun tìkára rẹ̀ sì ń dá wọn lóhùn.+  7  Ó ń bá a lọ ní bíbá wọn sọ̀rọ̀ nínú ọwọ̀n àwọsánmà.+Wọ́n pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti ìlànà tí ó fún wọn mọ́.+  8  Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, ìwọ tìkára rẹ dá wọn lóhùn.+Ọlọ́run tí ń dárí jini ni ìwọ jẹ́ sí wọn,+Ìwọ sì ń gbẹ̀san àwọn ohun olókìkí burúkú tí wọ́n ṣe.+  9  Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+Kí ẹ sì tẹrí ba níbi òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.+Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé