Sáàmù 98:1-9
Orin atunilára.
98 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+Nítorí pé àgbàyanu ni àwọn ohun tí ó ṣe.+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àní apá mímọ́ rẹ̀, ti jèrè ìgbàlà fún un.+
2 Jèhófà ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mímọ̀;+Ó ti ṣí òdodo rẹ̀ payá ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè.+
3 Ó ti rántí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí ilé Ísírẹ́lì.+Gbogbo òpin ilẹ̀ ayé ti rí ìgbàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run wa.+
4 Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+Ẹ tújú ká, kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, kí ẹ sì kọ orin atunilára.+
5 Ẹ fi háàpù kọ orin atunilára sí Jèhófà,+Pẹ̀lú háàpù àti ohùn orin atunilára.+
6 Pẹ̀lú kàkàkí àti ìró ìwo+Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun níwájú Ọba náà, Jèhófà.
7 Kí òkun sán ààrá àti ohun tí ó kún inú rẹ̀,+Ilẹ̀ eléso àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+
8 Kí àwọn odò pàápàá pàtẹ́wọ́;Àní kí gbogbo àwọn òkè ńlá lápapọ̀ fi ìdùnnú ké jáde+
9 Níwájú Jèhófà, nítorí pé ó ti wá láti ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé.+Òun yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ eléso,+Yóò sì fi ìdúróṣánṣán ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.+

