Sáàmù 94:1-23
94 Jèhófà, Ọlọ́run tí ń gbẹ̀san,+Ọlọ́run tí ń gbẹ̀san, tàn yanran!+
2 Gbé ara rẹ nà ró, ìwọ Onídàájọ́ ilẹ̀ ayé.+Mú ẹ̀san iṣẹ́ padà wá sórí àwọn onírera.+
3 Jèhófà, yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ẹni burúkú,+Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ẹni burúkú alára yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà?+
4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ yàùyàù, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láìníjàánu;+Gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ ń fọ́nnu nípa ara wọn.+
5 Jèhófà, wọ́n ń tẹ àwọn ènìyàn rẹ mọ́lẹ̀,+Wọ́n sì ń ṣẹ́ ogún rẹ níṣẹ̀ẹ́.+
6 Wọ́n pa opó àti àtìpó,+Wọ́n sì ṣìkà pa àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba.+
7 Wọ́n sì ń wí pé: “Jáà kò rí i;+Ọlọ́run Jékọ́bù kò sì lóye rẹ̀.”+
8 Kí ẹ lóye, ẹ̀yin aláìnírònú nínú àwọn ènìyàn;+Àti ní ti ẹ̀yin arìndìn, ìgbà wo ni ẹ óò ní ìjìnlẹ̀ òye èyíkéyìí?+
9 Ẹni tí ó gbin etí, ṣé kò lè gbọ́ ni?+Tàbí kẹ̀, Ẹni tí ó ṣẹ̀dá ojú, ṣé kò lè rí ni?+
10 Ẹni tí ń tọ́ àwọn orílẹ̀-èdè sọ́nà, ṣé kò lè fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ni,+Àní Ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀?+
11 Jèhófà mọ ìrònú àwọn ènìyàn, pé bí èémí àmíjáde ni wọ́n jẹ́.+
12 Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ìwọ tọ́ sọ́nà,+ Jáà,Àti ẹni tí ìwọ kọ́ láti inú òfin rẹ,+
13 Láti fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ kúrò nínú àwọn ọjọ́ ìyọnu àjálù,+Títí a ó fi wa kòtò sílẹ̀ fún ẹni burúkú.+
14 Nítorí pé Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì,+Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ogún tirẹ̀ sílẹ̀.+
15 Nítorí pé ìpinnu ìdájọ́ yóò padà àní sí òdodo,+Gbogbo àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
16 Ta ni yóò dìde fún mi ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn aṣebi?+Ta ni yóò mú ìdúró rẹ̀ fún mi ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́?+
17 Bí kò ṣe pé Jèhófà ti jẹ́ ìrànwọ́ fún mi,+Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ọkàn mi ì bá ti máa gbé inú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.+
18 Nígbà tí mo wí pé: “Ṣe ni ẹsẹ̀ mi yóò máa rìn tàgétàgé,”+Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni ó ń gbé mi ró.+
19 Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi,+Ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.+
20 Ìtẹ́ tí ń fa àgbákò yóò ha ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ+Bí ó ti ń fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n?+
21 Wọ́n ń gbéjà ko ọkàn olódodo lọ́nà mímúná,+Wọ́n sì ń pe ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ pàápàá ní ohun burúkú.+
22 Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò di ibi gíga ààbò fún mi,+Ọlọ́run mi yóò sì di àpáta ìsádi mi.+
23 Òun yóò sì yí ọṣẹ́ wọn dà sí wọn lórí,+Yóò sì fi ìyọnu àjálù tiwọn pa wọ́n lẹ́nu mọ́.+Jèhófà Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n lẹ́nu mọ́.+

