Sáàmù 93:1-5
93 Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba!+Ó gbé ọlá ògo wọ̀;+Jèhófà gbé e wọ̀—ó ti fi okun di ara rẹ̀ lámùrè.+Ilẹ̀ eléso pẹ̀lú di èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in tí a kò fi lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+
2 Ìtẹ́ rẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn;+Ìwọ wà láti àkókò tí ó lọ kánrin.+
3 Àwọn odò gbé e sókè, Jèhófà,Àwọn odò gbé ìró wọn sókè;+Àwọn odò ń gbé ìró ìbìlù wọn sókè ṣáá.+
4 Lékè àwọn ìró alagbalúgbú omi, ọlọ́lá ńlá ìgbì òkun tí ń fọ́n ká di ìfóófòó,+Ọlọ́lá ńlá+ ni Jèhófà ní ibi gíga.
5 Àwọn ìránnilétí rẹ ti já sí aṣeégbẹ́kẹ̀lé+ gan-an.Ìjẹ́mímọ́ yẹ ilé rẹ,+ Jèhófà, fún ọjọ́ gígùn.+

