Sáàmù 92:1-15
Orin atunilára, orin, fún ọjọ́ sábáàtì.
92 Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà+Àti láti máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ;+
2 Láti máa sọ̀rọ̀ nípa inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́+ ní òwúrọ̀Àti nípa ìṣòtítọ́ rẹ ní òròòru,+
3 Lórí ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá àti lórí gòjé,+Nípasẹ̀ ohùn orin adún-lọ-rére lórí háàpù.+
4 Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ti mú kí n máa yọ̀ nítorí ìgbòkègbodò rẹ;Mo ń fi ìdùnnú ké jáde nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+
5 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà!+Ìrònú rẹ jinlẹ̀ gidigidi.+
6 Kò sí aláìnírònú tí ó lè mọ̀ wọ́n,+Kò sì sí arìndìn tí ó lè lóye èyí.+
7 Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bí ewéko,+Tí gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ bá sì yọ ìtànná,Kí a lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú títí láé ni.+
8 Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà, ń bẹ ní ibi gíga lókè fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
9 Nítorí, wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ, Jèhófà,+Nítorí, wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;+Gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ ni a óò pín níyà sí ara wọn.+
10 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò gbé ìwo mi ga bí ti akọ màlúù ìgbẹ́;+Èmi yóò fi ọ̀tun òróró kunra.+
11 Ojú mi yóò sì máa wo àwọn ọ̀tá mi;+Etí mi yóò gbọ́ nípa àwọn ènìyàn náà gan-an tí ó dìde sí mi, àní àwọn aṣebi.
12 Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ;+Gẹ́gẹ́ bí kédárì ní Lẹ́bánónì, òun yóò di ńlá.+
13 Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà,+Nínú àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa,+ wọn yóò yọ ìtànná.
14 Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú,+Wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀,+
15 Láti lè sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà.+Òun ni Àpáta mi,+ ẹni tí kò sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀.+

