Sáàmù 91:1-16

91  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀+ Ẹni Gíga Jù Lọ+Yóò rí ibùwọ̀ fún ara rẹ̀ lábẹ́ òjìji Olódùmarè.+   Ṣe ni èmi yóò wí fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi,+Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.”+   Nítorí pé òun tìkára rẹ̀ yóò dá ọ nídè kúrò nínú pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ,+Kúrò nínú àjàkálẹ̀ àrùn tí ń fa àgbákò.+   Òun yóò fi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ àfifò dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ rẹ,+Ìwọ yóò sì sá di abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀.+Òótọ́+ rẹ̀ yóò jẹ́ apata+ ńlá àti odi ààbò.   Ìwọ kì yóò fòyà ohunkóhun tí ń múni kún fún ìbẹ̀rùbojo ní òru,+Tàbí ọfà+ tí ń fò ní ọ̀sán,   Tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tí ń rìn nínú ìṣúdùdù,+Tàbí ìparun tí ń fini ṣe ìjẹ ní ọjọ́kanrí.+   Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú àní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹÀti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ;Kì yóò sún mọ́ ọ.+   Kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò máa fi wò ó,+Tí ìwọ yóò sì rí, àní ẹ̀san iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú.+   Nítorí tí ìwọ wí pé: “Jèhófà ni ibi ìsádi mi,”+Ìwọ ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé rẹ;+ 10  Ìyọnu àjálù kankan kì yóò dé bá ọ,+Àní àrùnkárùn kì yóò sún mọ́ àgọ́ rẹ.+ 11  Nítorí pé òun yóò pa àṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ,+Láti máa ṣọ́ ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.+ 12  Ọwọ́ wọn ni wọn yóò fi gbé ọ,+Kí ìwọ má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta kankan.+ 13  Ìwọ yóò rìn lórí ẹgbọrọ kìnnìún àti ṣèbé;+Ìwọ yóò tẹ ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ejò ńlá+ mọ́lẹ̀. 14  Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi,+Èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un.+Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.+ 15  Òun yóò ké pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn.+Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú wàhálà.+Èmi yóò gbà á sílẹ̀, èmi yóò sì ṣe é lógo.+ 16  Gígùn ọjọ́ ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,+Èmi yóò sì jẹ́ kí ó rí ìgbàlà mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé