Sáàmù 90:1-17
Àdúrà Mósè, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́.+
90 Jèhófà, ìwọ tìkára rẹ ti jẹ́ ibùgbé gidi fún wa+Ní ìran dé ìran.+
2 Àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá,+Tàbí kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí bí ilẹ̀ ayé+ àti ilẹ̀ eléso+ gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí,Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.+
3 Ìwọ mú kí ẹni kíkú padà di ohun àtẹ̀rẹ́,+Ìwọ sì wí pé: “Ẹ padà lọ, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn.”+
4 Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí kìkì àná nígbà tí ó bá kọjá,+Àti bí ìṣọ́ kan ní òru.+
5 Ìwọ ti gbá wọn lọ;+ wọ́n di oorun lásán-làsàn;+Ní òwúrọ̀, wọ́n dà bí koríko tútù tí ń yí padà.+
6 Ní òwúrọ̀, ó mú ìtànná jáde, yóò sì yí padà;+Ní ìrọ̀lẹ́, ó rọ, ó sì gbẹ dànù dájudájú.+
7 Nítorí pé a ti wá sí òpin nínú ìbínú rẹ,+Ìhónú rẹ sì ti yọ wá lẹ́nu.+
8 Ìwọ ti gbé ìṣìnà wa kalẹ̀ sí ọ̀gangan iwájú rẹ,+Àwọn nǹkan àṣírí wa sí iwájú rẹ tí ó mọ́lẹ̀ yòò.+
9 Nítorí pé gbogbo ọjọ́ wa ti ń lọ sí òpin wọn nínú ìbínú kíkan rẹ;+Àwa ti parí àwọn ọdún wa gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.+
10 Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún;+Bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá,+Síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́;+Nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.+
11 Ta ní ń bẹ tí ó mọ okun ìbínú rẹ+Àti ìbínú kíkan rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìbẹ̀rù rẹ?+
12 Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa+Ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.+
13 Padà, Jèhófà!+ Yóò ti pẹ́ tó?+Kí o sì kẹ́dùn nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+
14 Fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,+Kí a lè fi ìdùnnú ké jáde, kí a sì lè máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa.+
15 Mú kí a máa yọ̀ lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn ọjọ́ tí ìwọ fi ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́,+Àwọn ọdún tí a fi rí ìyọnu àjálù.+
16 Kí ìgbòkègbodò rẹ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ,+Kí ọlá ńlá rẹ sì hàn lára àwọn ọmọ wọn.+
17 Kí adùn Jèhófà Ọlọ́run wa sì wà lára wa,+Kí o sì fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in lára wa.+Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ ọwọ́ wa, kí o fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+

