Sáàmù 9:1-20
Sí olùdarí lórí Muti-lábénì. Orin atunilára ti Dáfídì.
א [Áléfì]
9 Ṣe ni èmi yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ, Jèhófà;+Èmi yóò máa polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+
2 Ṣe ni èmi yóò máa yọ̀, èmi yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú rẹ,+Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ.+
ב [Bétì]
3 Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi bá yí padà,+Wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣègbé kúrò níwájú rẹ.+
4 Nítorí pé o ti mú ìdájọ́ mi àti ẹjọ́ mi ṣẹ ní kíkún;+O ti jókòó sórí ìtẹ́ ní fífi òdodo ṣe ìdájọ́.+
ג [Gímélì]
5 O ti bá àwọn orílẹ̀-èdè wí lọ́nà mímúná,+ o ti pa ẹni burúkú run.+Orúkọ wọn ni o ti nù kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+
6 Ìwọ ọ̀tá, ìsọdahoro rẹ ni a ti ṣe ni àṣepé títí lọ fáàbàdà,+Àti àwọn ìlú ńlá tí o ti fà tu.+Àní mímẹ́nukàn wọ́n yóò ṣègbé dájúdájú.+
ה [Híì]
7 Ní ti Jèhófà, yóò jókòó fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Ní fífìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún ìdájọ́ pàápàá.+
8 Òun fúnra rẹ̀ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ eléso ní òdodo;+Yóò ṣe ìgbẹ́jọ́ àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè ní ìdúróṣánṣán.+
ו [Wọ́ọ̀]
9 Jèhófà yóò sì di ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára,+Ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà.+
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ,+Nítorí tí ìwọ, Jèhófà, kì yóò fi àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀ dájúdájú.+
ז [Sáyínì]
11 Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, ẹni tí ń gbé Síónì;+Ẹ sọ àwọn ìṣe rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn.+
12 Nítorí pé, nígbà tí ó bá ń wá ìtàjẹ̀sílẹ̀,+ dájúdájú, òun yóò rántí àwọn wọ̀nyẹn gan-an;+Ó dájú pé kò ní gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+
ח [Kétì]
13 Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà; rí ìṣẹ́ tí àwọn tí ó kórìíra mi fi ń ṣẹ́ mi,+Ìwọ tí ń gbé mi sókè láti àwọn ẹnubodè ikú,+
14 Kí n lè polongo gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó yẹ fún ìyìn+Ní àwọn ẹnubodè+ ọmọbìnrin Síónì,+Kí n lè kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ.+
ט [Tétì]
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti rì sínú kòtò tí wọ́n gbẹ́;+Inú àwọ̀n+ tí wọ́n fi pa mọ́, ni a ti gbá ẹsẹ̀ àwọn fúnra wọn mú.+
16 Jèhófà ni a mọ̀ nípasẹ̀ ìdájọ́ tí ó ti mú ṣẹ ní kíkún.+Nípasẹ̀ ìgbòkègbodò ọwọ́ ara rẹ̀ ni a fi dẹkùn mú ẹni burúkú.+Hígáíónì. Sélà.
י [Yódì]
17 Àwọn ènìyàn burúkú+ yóò padà sí Ṣìọ́ọ̀lù,+Àní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá gbàgbé Ọlọ́run.+
18 Nítorí pé a kì yóò fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn òtòṣì,+Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn ọlọ́kàn tútù kì yóò ṣègbé láé.+
כ [Káfì]
19 Dìde, Jèhófà! Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú fi àjùlọ hàn nínú okun.+Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ.+
20 Dẹ́rù bà wọ́n, Jèhófà,+Kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ pé ẹni kíkú lásán ni wọ́n.+ Sélà.

