Sáàmù 89:1-52
Másíkílì. Ti Étánì tí í ṣe Ẹ́síráhì.+
89 Àwọn ìfihàn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni èmi yóò máa fi ṣe orin kọ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Ní ìran dé ìran ni èmi yóò máa fi ẹnu mi sọ ìṣòtítọ́ rẹ di mímọ̀.+
2 Nítorí èmi ti wí pé: “A óò gbé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin;+Ní ti ọ̀run, ìwọ fìdí ìṣòtítọ́ rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú rẹ̀.”+
3 “Èmi ti bá àyànfẹ́ mi dá májẹ̀mú;+Èmi ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi+ pé,
4 ‘Àní fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,+Ṣe ni èmi yóò sì gbé ìtẹ́ rẹ ró+ ní ìran dé ìran.’” Sélà.
5 Ọ̀run yóò sì gbé ohun ìyanu tí ìwọ ṣe lárugẹ, Jèhófà,+Bẹ́ẹ̀ ni, ìṣòtítọ́ rẹ nínú ìjọ àwọn ẹni mímọ́.
6 Nítorí pé ta ni ó wà ní sánmà tí a lè fi wé Jèhófà?+Ta ni ó lè jọ Jèhófà lára àwọn ọmọ Ọlọ́run?+
7 Ọlọ́run ni kí a ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ní àwùjọ tímọ́tímọ́ ti àwọn ẹni mímọ́;+Ó jẹ́ atóbilọ́lá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù lórí gbogbo àwọn tí ó yí i ká.+
8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+Ta ni ó ní okun inú bí ìwọ, Jáà?+Ìṣòtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.+
9 Ìwọ ń ṣàkóso lórí ìrusókè òkun;+Nígbà tí ó bá gbé ìgbì rẹ̀ dìde, ìwọ tìkára rẹ ni ó ń mú un pa rọ́rọ́.+
10 Ìwọ tìkára rẹ ti tẹ Ráhábù rẹ́,+ àní gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a pa.+Ìwọ ti fi apá okun rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.+
11 Tìrẹ ni ọ̀run,+ tìrẹ sì ni ilẹ̀ ayé pẹ̀lú;+Ilẹ̀ eléso àti ohun tí ó kún inú rẹ̀+—ìwọ tìkára rẹ ni ó fi ìpìlẹ̀ wọn sọlẹ̀.+
12 Àríwá àti gúúsù—ìwọ tìkára rẹ ni ó dá wọn;+Tábórì+ àti Hámónì+—wọ́n ń fi ìdùnnú ké jáde ní orúkọ rẹ.+
13 Apá tí ó ní agbára ńlá jẹ́ tìrẹ,+Ọwọ́ rẹ le,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni a gbé ga.+
14 Òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;+Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ wá sí iwájú rẹ.+
15 Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú.+Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn.+
16 Wọ́n ń kún fún ìdùnnú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní orúkọ rẹ,+A sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.+
17 Nítorí pé ìwọ ni ẹwà okun wọn;+Nípa ìfẹ́ rere rẹ ni a sì fi gbé ìwo wa ga.+
18 Nítorí pé ti Jèhófà ni apata wa,+Ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni ọba wa.+
19 Ní àkókò yẹn, ìwọ bá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sọ̀rọ̀ nínú ìran,+Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé:“Èmi ti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún alágbára ńlá;+Èmi ti gbé àyànfẹ́ kan ga nínú àwọn ènìyàn.+
20 Èmi ti rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;+Èmi ti fi òróró mímọ́ mi yàn án,+
21 Ẹni tí ọwọ́ mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in,+Ẹni tí apá tèmi yóò fún lókun pẹ̀lú.+
22 Ọ̀tá kankan kì yóò fi tipátipá gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀,+Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ àìṣòdodo èyíkéyìí kì yóò ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́.+
23 Èmi sì fọ́ àwọn elénìní rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ kúrò níwájú rẹ̀,+Mo sì ń mú ìyọnu àgbálù bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ lọ́nà gbígbóná janjan.+
24 Ìṣòtítọ́ mi àti inú rere mi onífẹ̀ẹ́ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,+Orúkọ mi ni a sì fi gbé ìwo rẹ̀ ga.+
25 Èmi sì ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé òkun+Àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé àwọn odò.+
26 Òun fúnra rẹ̀ ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,+Ọlọ́run mi+ àti Àpáta ìgbàlà mi.’+
27 Pẹ̀lúpẹ̀lù, èmi alára yóò fi í ṣe àkọ́bí,+Ẹni gíga jù lọ nínú àwọn ọba ilẹ̀ ayé.+
28 Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò pa inú rere mi onífẹ̀ẹ́ mọ́ sí i,+Májẹ̀mú mi yóò sì jẹ́ aṣeégbíyèlé sí i.+
29 Dájúdájú, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé+Àti ìtẹ́ rẹ̀ bí àwọn ọjọ́ ọ̀run.+
30 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi òfin mi sílẹ̀,+Tí wọn kò sì rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi,+
31 Bí wọ́n bá sọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ tèmi di aláìmọ́,Tí wọn kò sì pa àwọn àṣẹ tèmi mọ́,
32 Èmi yóò sì fi ọ̀pá yí àfiyèsí mi sí ìrélànàkọjá wọn,+Àní èmi yóò fi ẹgba yí àfiyèsí mi sí ìṣìnà wọn.+
33 Ṣùgbọ́n inú rere mi onífẹ̀ẹ́ ni èmi kì yóò mú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,+Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò já sí èké ní ti ìṣòtítọ́ mi.+
34 Èmi kì yóò sọ májẹ̀mú mi di aláìmọ́,+Èmi kì yóò sì yí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó ti ètè mi jáde padà.+
35 Ẹ̀ẹ̀kan ni mo ti fi ìjẹ́mímọ́ mi búra,+Èmi kì yóò purọ́ fún Dáfídì.+
36 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Àti ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oòrùn ní iwájú mi.+
37 A ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in gẹ́gẹ́ bí òṣùpá fún àkókò tí ó lọ kánrin,Àti gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà.” Sélà.
38 Ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ ti ta nù, ìwọ sì ń fojú pa rẹ́;+Ìwọ ti bínú kíkankíkan sí ẹni àmì òróró rẹ.+
39 Ìwọ ti kọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ sílẹ̀ tẹ̀gàntẹ̀gàn;Ìwọ ti sọ adé dáyádémà rẹ̀ di aláìmọ́ títí dé ilẹ̀yílẹ̀.+
40 Ìwọ ti wó gbogbo ọgbà ẹran rẹ̀ tí a fi òkúta ṣe lulẹ̀+;Ìwọ ti mú ìparun bá àwọn odi rẹ̀.+
41 Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ lójú ọ̀nà ti kó o ní ìkógun;+Ó ti di ẹ̀gàn sí àwọn aládùúgbò rẹ̀.+
42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún àwọn elénìní rẹ̀ ga;+Ìwọ ti mú kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ máa yọ̀.+
43 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ tún hùwà sí idà rẹ̀ bí ọ̀tá,+Ìwọ sì ti mú kí ó má ṣe ní ìtẹ̀síwájú nínú ìjà ogun.+
44 Ìwọ ti mú kí ó pàdánù ìdángbinrin rẹ̀,+Ìtẹ́ rẹ̀ ni ìwọ sì ti fi sọ̀kò sí ilẹ̀yílẹ̀.+
45 Ìwọ ti ké àwọn ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;Ìwọ ti fi ìtìjú bò ó.+ Sélà.
46 Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìwọ yóò máa bá a nìṣó ní fífi ara rẹ pa mọ́? Ṣé títí lọ ni?+Ìhónú rẹ yóò ha máa bá a nìṣó ní jíjó bí iná?+
47 Rántí ibi tí ọjọ́ ayé mi mọ.+Lásán ha ni ìwọ dá gbogbo ọmọ ènìyàn bí?+
48 Abarapá ọkùnrin wo ni ó wà láàyè tí kì yóò rí ikú?+Ó ha lè pèsè àsálà fún ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Ṣìọ́ọ̀lù bí?+ Sélà.
49 Àwọn ìṣe inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ti àtijọ́ dà, Jèhófà,Èyí tí o búra nípa rẹ̀ fún Dáfídì nínú ìṣòtítọ́ rẹ?+
50 Jèhófà, rántí ẹ̀gàn tí ń bẹ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ,+Rírù tí mo ń ru ẹ̀gàn gbogbo àwọn ènìyàn púpọ̀ ní oókan àyà mi,+
51 Bí àwọn ọ̀tá rẹ ti pẹ̀gàn, Jèhófà,+Bí wọ́n ti pẹ̀gàn àwọn ojú ẹsẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.+
52 Ìbùkún ni fún Jèhófà fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àmín àti Àmín.+

