Sáàmù 87:1-7
Ti àwọn ọmọ Kórà. Orin atunilára, orin.
87 Ìpìlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ ní àwọn òkè ńlá mímọ́.+
2 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè Síónì gidigidi+Ju gbogbo àgọ́ Jékọ́bù.+
3 Àwọn ohun ológo ni a ń sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú ńlá Ọlọ́run tòótọ́.+ Sélà.
4 Èmi yóò mẹ́nu kan Ráhábù+ àti Bábílónì+ pé wọ́n wà lára àwọn tí ó mọ̀ mí;Filísíà+ àti Tírè nìyí, pa pọ̀ pẹ̀lú Kúṣì:“Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.”+
5 Àti ní ti Síónì, a óò wí pé:“Gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni a bí nínú rẹ̀.”+Ẹni Gíga Jù Lọ+ tìkára rẹ̀ yóò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+
6 Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò polongo, nígbà ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn+ pé:“Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.”+ Sélà.
7 Àwọn akọrin àti àwọn tí ń jó ijó àjóyípo yóò wà:+“Gbogbo ìsun mi ń bẹ nínú rẹ.”+

