Sáàmù 83:1-18

Orin. Orin atunilára ti Ásáfù.+ 83  Ọlọ́run, má ṣe jẹ́ kí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ wà níhà ọ̀dọ̀ rẹ;+Má ṣe máa bá a nìṣó ní ṣíṣàìsọ̀rọ̀, má sì dúró jẹ́ẹ́, Olú Ọ̀run.+  2  Nítorí, wò ó! àní àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀;+Àní àwọn tí ó kórìíra rẹ lọ́nà gbígbóná janjan ti gbé orí wọn sókè.+  3  Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ àṣírí wọn lọ lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí lòdì sí àwọn ènìyàn rẹ;+Wọ́n sì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí àwọn tí ìwọ fi pa mọ́.+  4  Wọ́n ti wí pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a pa wọ́n rẹ́ kúrò ní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè,+Kí a má bàa rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”+  5  Nítorí pé wọ́n ti fi ọkàn-àyà gbìmọ̀ pọ̀ ní ìsopọ̀ṣọ̀kan;+Àní wọ́n tẹ̀ síwájú láti dá májẹ̀mú lòdì sí ọ,+  6  Àwọn àgọ́ Édómù+ àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti ti àwọn ọmọ Hágárì,+  7  Gébálì àti Ámónì+ àti Ámálékì,Filísíà+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùgbé Tírè.+  8  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Ásíríà alára ti dara pọ̀ mọ́ wọn;+Wọ́n ti di apá kan ṣoṣo fún àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì.+ Sélà.  9  Ṣe wọ́n bí ti Mídíánì,+ bí ti Sísérà,+Bí ti Jábínì+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì.+ 10  A pa wọ́n rẹ́ ráúráú ní Ẹ́ń-dórì;+Wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀.+ 11  Ní ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú wọn, ṣe àwọn wọ̀nyí bí Órébù àti bí Séébù,+Àti bí Séébà àti bí Sálímúnà gbogbo àwọn mọ́gàjí wọn,+ 12  Tí wọ́n ti wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba àwọn ibi gbígbé Ọlọ́run fún ara wa.”+ 13  Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wọ́n bí òṣùṣú tí ààjà ń gbé kiri,+Bí àgékù pòròpórò níwájú ẹ̀fúùfù.+ 14  Bí iná tí ń jó igbó+Àti bí ọwọ́ iná tí ń jó àwọn òkè ńlá gbẹ,+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni kí o fi ìjì líle rẹ lépa wọn,+Kí o sì fi ẹ̀fúùfù rẹ oníjì yọ wọ́n lẹ́nu.+ 16  Fi àbùkù kún ojú wọn,+Kí àwọn ènìyàn lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.+ 17  Kí ojú tì wọ́n, kí a sì yọ wọ́n lẹ́nu ní ìgbà gbogbo,+Kí wọ́n sì tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé;+ 18  Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀+ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,+Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ+ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé