Sáàmù 82:1-8
Orin atunilára ti Ásáfù.
82 Ọlọ́run dúró nínú àpéjọ+ Olú Ọ̀run;+Ó ń ṣe ìdájọ́ ní àárín àwọn ọlọ́run+ pé:
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa fi àìṣèdájọ́ òdodo dáni lẹ́jọ́,+Tí ẹ ó sì máa ṣe ojúsàájú àwọn ẹni burúkú?+ Sélà.
3 Ẹ jẹ́ onídàájọ́ fún ẹni rírẹlẹ̀ àti ọmọdékùnrin aláìníbaba.+Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́.+
4 Ẹ pèsè àsálà fún ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì;+Ẹ dá wọn nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ẹni burúkú.”+
5 Wọn kò mọ̀, wọn kò sì lóye;+Inú òkùnkùn ni wọ́n ti ń rìn káàkiri;+Gbogbo ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé ni a mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+
6 “Èmi alára ti wí pé, ‘Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́run,+Gbogbo yín sì jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.+
7 Ṣe ni ẹ óò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn;+Ẹ ó sì ṣubú bí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ aládé!’”+
8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé;+Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ yóò gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ìní.+

