Sáàmù 79:1-13
Orin atunilára ti Ásáfù.
79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá sínú ogún rẹ;+Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin;+Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di òkìtì àwókù.+
2 Wọ́n ti fi òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run,+Wọ́n ti fi ẹran ara àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ fún àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé.+
3 Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn jáde bí omiNí gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù, kò sì sí ẹnì kankan láti sìnkú.+
4 Àwa ti di ẹ̀gàn fún àwọn aládùúgbò wa,+Ẹni ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣeyẹ̀yẹ́ fún àwọn tí ó wà yí wa ká.+
5 Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìbínú rẹ yóò máa ru sókè? Ṣé títí láé ni?+Yóò ti pẹ́ tó tí ìgbóná-ọkàn rẹ yóò máa jó gẹ́gẹ́ bí iná?+
6 Da ìhónú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,+Àti sórí àwọn ìjọba tí kò ké pe orúkọ rẹ.+
7 Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run,+Wọ́n sì ti mú kí ibi gbígbé rẹ̀ di ahoro.+
8 Má ṣe rántí ìṣìnà àwọn baba ńlá wa ìgbàanì sí wa.+Ṣe wéré! Jẹ́ kí àánú rẹ bá wa pàdé,+Nítorí pé a ti di òtòṣì gidigidi.+
9 Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa,+Nítorí ògo orúkọ rẹ;+Kí o sì dá wa nídè, kí o sì bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní tìtorí orúkọ rẹ.+
10 Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi sọ pé: “Ọlọ́run wọn dà?”+Láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lójú wa,+Ìgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí a ti ta sílẹ̀.+
11 Kí ìmí ẹ̀dùn ẹlẹ́wọ̀n wọlé wá àní síwájú rẹ.+Gẹ́gẹ́ bí títóbi apá rẹ, pa àwọn tí a yàn kalẹ̀ fún ikú mọ́.+
12 Kí o sì san án padà fún àwọn aládùúgbò wa ní ìgbà méje sí oókan àyà wọn,+Ẹ̀gàn wọn tí wọ́n ti fi gàn ọ́, Jèhófà.+
13 Ní ti àwa ènìyàn rẹ àti agbo ẹran pápá ìjẹko rẹ,+Àwa yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ dé àkókò tí ó lọ kánrin;Láti ìran dé ìran ni àwa yóò máa polongo ìyìn rẹ.+

