Sáàmù 78:1-72
Másíkílì. Ti Ásáfù.+
78 Ẹ fi etí sí òfin mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;+Ẹ dẹ etí sí àwọn àsọjáde ẹnu mi.+
2 Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi nínú ọ̀rọ̀ òwe;+Èmi yóò sì mú kí àwọn àlọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn tú jáde,+
3 Èyí tí a ti gbọ́ tí a sì mọ̀,+Èyí tí àwọn baba wa sì ti ṣèròyìn fún wa;+
4 Èyí tí àwa kò fi pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn,+Tí a ń ṣèròyìn wọn àní fún ìran tí ń bọ̀,+Ìyìn Jèhófà àti okun rẹ̀+Àti àwọn ohun àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe.+
5 Ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé ìránnilétí kan dìde ní Jékọ́bù,+Ó sì gbé òfin kan kalẹ̀ ní Ísírẹ́lì,+Àwọn ohun tí ó pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,+Pé kí wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ wọn;+
6 Kí ìran tí ń bọ̀, àwọn ọmọ tí a óò bí, lè mọ̀ wọ́n,+Kí wọ́n lè dìde, kí wọ́n sì ṣèròyìn wọn fún àwọn ọmọ wọn,+
7 Kí wọ́n sì lè gbé ìgbọ́kànlé wọn ka Ọlọ́run tìkára rẹ̀,+Kí wọ́n má sì gbàgbé àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run,+ bí kò ṣe pé kí wọ́n máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+
8 Kí wọ́n má sì dà bí àwọn baba ńlá wọn,+Ìran alágídí àti ọlọ̀tẹ̀,+Ìran tí kò múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀,+Tí ẹ̀mí wọn kò sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé níwájú Ọlọ́run.+
9 Àwọn ọmọ Éfúráímù, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ olùta ọrun tí ó ti dìhámọ́ra,+Sá padà ní ọjọ́ ìjà.+
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́,+Wọ́n sì kọ̀ láti máa rìn nínú òfin rẹ̀.+
11 Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé ìbálò rẹ̀+Àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ tí ó jẹ́ kí wọ́n rí.+
12 Ó ṣe ohun ìyanu ní iwájú àwọn baba ńlá wọn+Ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ àní pápá Sóánì.+
13 Ó pín òkun níyà, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n ré kọjá,+Ó sì mú kí omi dúró bí ìsédò.+
14 Ó ń bá a lọ ní fífi àwọsánmà ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán+Àti ìmọ́lẹ̀ iná ní gbogbo òru.+
15 Ó tẹ̀ síwájú láti la àpáta ní aginjù,+Kí ó lè mú kí wọ́n mu ọ̀pọ̀ yanturu gẹ́gẹ́ bí ibú omi.+
16 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìṣàn omi jáde wá láti inú àpáta gàǹgà,+Ó sì ń mú kí omi ṣàn gẹ́gẹ́ bí àwọn odò.+
17 Wọ́n sì tún ń bá a nìṣó ní títúbọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí i,+Nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ ní ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi;+
18 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dán Ọlọ́run wò nínú ọkàn-àyà wọn,+Nípa bíbéèrè fún nǹkan jíjẹ fún ọkàn wọn.+
19 Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run.+Wọ́n wí pé: “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì nínú aginjù bí?”+
20 Wò ó! Ó lu àpáta,+Kí omi lè ṣàn, kí àwọn ọ̀gbàrá sì lè ya jáde.+“Ó ha lè fúnni ní oúnjẹ pẹ̀lú bí,+Tàbí ó ha lè pèsè ohun ìgbẹ́mìíró sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”+
21 Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi gbọ́, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bínú kíkankíkan;+A sì mú kí iná jó Jékọ́bù,+Ìbínú sì ru sí Ísírẹ́lì pẹ̀lú.+
22 Nítorí tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,+Wọn kò sì gbẹ́kẹ̀ lé ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.+
23 Ó sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀ lókè,Àní ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run.+
24 Ó sì ń rọ̀jò mánà lé wọn lórí ṣáá láti jẹ,+Ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run.+
25 Àní àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn alágbára;+Ó fi ìpèsè oúnjẹ ránṣẹ́ sí wọn tẹ́rùntẹ́rùn.+
26 Ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn rọ́ jáde ní ọ̀run,+Ó sì mú kí ẹ̀fúùfù gúúsù fẹ́ nípasẹ̀ okun tirẹ̀.+
27 Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí ohun ìgbẹ́mìíró rọ̀ lé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí ekuru,+Àní àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń fò, gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn òkun.+
28 Ó sì ń bá a nìṣó ní mímú kí wọ́n bọ́ sí àárín ibùdó rẹ̀,+Ní gbogbo àyíká àwọn àgọ́ rẹ̀.+
29 Wọ́n sì ń jẹ, wọ́n sì ń tẹ́ ara wọn lọ́rùn gidigidi,+Ohun tí wọ́n ní ìfẹ́-ọkàn sí ni ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wá fún wọn.+
30 Wọn kò yí padà kúrò nínú ìfẹ́-ọkàn wọn,Nígbà tí oúnjẹ wọ́n ṣì wà ní ẹnu wọn,+
31 Nígbà tí ìrunú Ọlọ́run ru sí wọn,+Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa lára àwọn tí ó táagun nínú wọn;+Ó sì mú kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ísírẹ́lì wó lulẹ̀.
32 Láìka gbogbo èyí sí, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,+Wọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+
33 Nítorí náà, ó mú ọjọ́ wọn wá sí òpin bí èémí àmíjáde lásán-làsàn,+Àti ọdún wọn nípa ìyọlẹ́nu.
34 Nígbàkúùgbà tí ó bá pa wọ́n, àwọn pẹ̀lú a ṣe ìwádìí nípa rẹ̀,+Wọn a sì padà, wọn a sì wá Ọlọ́run.+
35 Wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí rántí pé Ọlọ́run ni Àpáta wọn,+Àti pé Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùgbẹ̀san wọn.+
36 Wọ́n sì gbìyànjú láti fi ẹnu wọn tàn án;+Wọ́n sì gbìyànjú láti fi ahọ́n wọn purọ́ fún un.+
37 Ọkàn-àyà wọn kò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;+Wọn kò sì jẹ́ aṣeégbíyèlé nínú májẹ̀mú rẹ̀.+
38 Ṣùgbọ́n ó jẹ́ aláàánú;+ òun a sì bo ìṣìnà+ náà, kì yóò sì mú ìparun wá.+Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì mú kí ìbínú rẹ̀ yí padà,+Kì í sì í ru gbogbo ìhónú rẹ̀ dìde.
39 Ó sì ń bá a nìṣó ní rírántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,+Pé ẹ̀mí ń jáde lọ, kì í sì í padà wá.+
40 Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó,+Wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́ ní aṣálẹ̀!+
41 Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò,+Àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
42 Wọn kò rántí ọwọ́ rẹ̀,+Ní ọjọ́ tí ó tún wọn rà padà láti ọwọ́ elénìní,+
43 Bí ó ṣe fi àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ sí Íjíbítì+Àti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí pápá Sóánì;+
44 Àti bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ipa odò Náílì wọn di ẹ̀jẹ̀,+Tí wọn kò fi lè mu láti inú àwọn ìṣàn omi tiwọn.+
45 Ó sì tẹ̀ síwájú láti rán àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ sí wọn, kí ìwọ̀nyí lè jẹ wọ́n run;+Àti àwọn àkèré, kí ìwọ̀nyí lè run wọ́n.+
46 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi èso wọn fún aáyán,Àti làálàá wọn fún eéṣú.+
47 Àní ó bẹ̀rẹ̀ sí fi yìnyín pa àjàrà wọn,+Ó sì fi àwọn òkúta yìnyín pa àwọn igi síkámórè wọn.+
48 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ẹranko arẹrù wọn lé yìnyín lọ́wọ́,+Àti ohun ọ̀sìn wọn fún ibà amáragbóná fòfò.
49 Ó ń bá a lọ ní rírán ìbínú rẹ̀ jíjófòfò sórí wọn,+Ìbínú kíkan àti ìdálẹ́bi àti wàhálà,+Àwùjọ àwọn áńgẹ́lì tí a rán láti mú ìyọnu àjálù wá.+
50 Ó tẹ̀ síwájú láti pèsè ipa ọ̀nà sílẹ̀ fún ìbínú rẹ̀.+Kò fa ọkàn wọn sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ ikú;Ó sì fi ìwàláàyè wọn lé àjàkálẹ̀ àrùn lọ́wọ́.+
51 Níkẹyìn, ó ṣá gbogbo àkọ́bí balẹ̀ ní Íjíbítì,+Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ agbára ìbímọ wọn nínú àwọn àgọ́ Hámù.+
52 Lẹ́yìn ìgbà náà, ó mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde lọ gẹ́gẹ́ bí agbo ẹran kan,+Ó sì darí wọn bí agbo ẹran ọ̀sìn kan ní aginjù.+
53 Ó sì ń ṣamọ̀nà wọn nínú ààbò, wọn kò sì ní ìbẹ̀rùbojo;+Òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn.+
54 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn wá sí ìpínlẹ̀ mímọ́ rẹ̀,+Ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá yìí, tí ó jẹ́ pé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ó ni ín.+
55 Àti nítorí wọn, ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀,+Ó sì ń bá a lọ láti fi okùn ìdiwọ̀n pín ogún fún wọn,+Tí ó fi mú kí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì máa gbé inú ilé tiwọn.+
56 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dán Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i,+Wọn kò sì pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ mọ́.+
57 Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ń yí padà ṣáá, wọ́n sì ń hùwà lọ́nà àdàkàdekè bí àwọn baba ńlá wọn;+Wọ́n yíjú padà bí ọrun dídẹ̀.+
58 Wọ́n sì ń fi àwọn ibi gíga wọn mú un bínú ṣáá,+Wọ́n sì ń fi àwọn ère fífín wọn ru ú lọ́kàn sókè sí owú ṣáá.+
59 Ọlọ́run gbọ́,+ ó sì bínú kíkankíkan,+Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fojú pa Ísírẹ́lì rẹ́ gidigidi.+
60 Níkẹyìn, ó sì ṣá àgọ́ ìjọsìn Ṣílò tì,+Àgọ́ tí ó ń gbé inú rẹ̀ láàárín ará ayé.+
61 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi okun rẹ̀ fún oko òǹdè pàápàá,+Ó sì fi ẹwà rẹ̀ lé elénìní lọ́wọ́.+
62 Ó sì ń fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,+Ó sì bínú kíkankíkan sí ogún rẹ̀.+
63 Iná jẹ àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ run,A kò sì fi ìyìn fún àwọn wúńdíá rẹ̀.+
64 Ní ti àwọn àlùfáà rẹ̀, wọ́n tipa idà ṣubú,+Àwọn opó wọn kò sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.+
65 Nígbà náà ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí jí bí ẹni pé kúrò lójú oorun,+Bí alágbára ńlá tí ọtí wáínì ń dá lójú rẹ̀.+
66 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn elénìní rẹ̀ balẹ̀ láti ẹ̀yìn;+Ẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ó kó bá wọn.+
67 Ó sì tẹ̀ síwájú láti kọ àgọ́ Jósẹ́fù;+Kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù.+
68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà,+Òkè Ńlá Síónì, èyí tí òun nífẹ̀ẹ́.+
69 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ibùjọsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ibi gíga,+Bí ilẹ̀ ayé tí ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
70 Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yan Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀,+Ó sì mú un kúrò nínú àwọn ọgbà agbo ẹran.+
71 Kúrò ní títọ àwọn abo tí ń fọ́mọ lọ́mú lẹ́yìn,+Ó mú un wá láti jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lórí Jékọ́bù ènìyàn rẹ̀+Àti lórí Ísírẹ́lì ogún rẹ̀.+
72 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà rẹ̀,+Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìjáfáfá ọwọ́ rẹ̀ ṣamọ̀nà wọn.+

