Sáàmù 73:1-28

Orin atunilára ti Ásáfù.+ 73  Ní tòótọ́, Ọlọ́run ṣe rere fún Ísírẹ́lì, fún àwọn tí ó mọ́ ní ọkàn-àyà.+   Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà,+Díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.+   Nítorí ti èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo,+Nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.+   Nítorí tí wọn kì í ní ìroragógó ikú;+Ikùn bẹ̀ǹbẹ̀ wọn sì yọ.+   Wọn kò tilẹ̀ sí nínú ìdààmú ẹni kíkú,+Ìyọnu kì í sì í bá wọn bí ti àwọn ènìyàn mìíràn.+   Nítorí náà ni ìrera fi dà bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún wọn;+Ìwà ipá bò wọ́n kanlẹ̀ bí ẹ̀wù.+   Ojú wọn yọ jáde fún ìsanra;+Wọ́n ti ré kọjá ààlà ohun tí ọkàn-àyà lè rò.+   Wọ́n ń fini rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó burú;+Wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa jìbìtì lọ́nà ìfẹgẹ̀.+   Wọ́n ti gbé ẹnu wọn àní sí ọ̀run,+Ahọ́n wọn pàápàá sì ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé.+ 10  Nítorí náà, ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ padà wá sí ìhín,A sì ń gbọ́n omi ohun tí ó kún fún wọn. 11  Wọ́n sì ti wí pé: “Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe mọ̀?+Ìmọ̀ ha sì wà nínú Ẹni Gíga Jù Lọ bí?”+ 12  Wò ó! Àwọn wọ̀nyí ni ẹni burúkú, àwọn tí ó wà ní ìdẹ̀rùn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Wọ́n ti mú kí àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn pọ̀ sí i.+ 13  Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́,+Tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀.+ 14  Ìyọnu sì ń bá mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,+Mo sì ń gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ní òròòwúrọ̀.+ 15  Ká ní mo ti wí pé: “Ṣe ni èmi yóò sọ irú ìtàn bẹ́ẹ̀,”Wò ó! ìran àwọn ọmọ rẹNi èmi ì bá ti hùwà lọ́nà àdàkàdekè sí.+ 16  Mo sì ń gbèrò ṣáá láti mọ èyí;+Ó jẹ́ ìdààmú ní ojú mi, 17  Títí mo fi wá sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.+Mo fẹ́ láti fi òye mọ ọjọ́ ọ̀la wọn.+ 18  Dájúdájú, orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni ibi tí ìwọ gbé wọn kà.+Ìwọ ti mú kí wọ́n ṣubú ní rírún wómúwómú.+ 19  Ẹ wo bí wọ́n ti di ohun ìyàlẹ́nu bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!+Ẹ wo bí wọ́n ti dé òpin wọn, tí a mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì! 20  Bí àlá lẹ́yìn jíjí, Jèhófà,+Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò tẹ́ńbẹ́lú ère wọn nígbà tí ìwọ bá ru dìde.+ 21  Nítorí tí ọkàn-àyà mi di kíkorò,+Kíndìnrín mi sì ro mí gógó,+ 22  Mo sì jẹ́ aláìnírònú, n kò sì lè mọ̀;+Mo dà bí ẹranko lásán-làsàn ní ojú ìwòye rẹ.+ 23  Ṣùgbọ́n èmi wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;+Ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.+ 24  Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi,+Lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.+ 25  Ta ni mo ní ní ọ̀run?+Yàtọ̀ sí ìwọ, èmi kò ní inú dídùn mìíràn lórí ilẹ̀ ayé.+ 26  Ẹ̀yà ara mi àti ọkàn-àyà mi ti kọṣẹ́.+Ọlọ́run ni àpáta ọkàn-àyà mi àti ìpín mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 27  Nítorí, wò ó! àní àwọn tí ń jìnnà sí ọ yóò ṣègbé.+Ṣe ni ìwọ yóò pa gbogbo àwọn tí ń ṣe ìṣekúṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ lẹ́nu mọ́.+ 28  Ṣùgbọ́n ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.+Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi,+Láti máa polongo gbogbo iṣẹ́ rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé