Sáàmù 69:1-36
Sí olùdarí lórí Òdòdó Lílì.+ Ti Dáfídì.
69 Gbà mí là, Ọlọ́run, nítorí pé omi ti wá títí dé ọkàn.+
2 Mo ti rì sínú ẹrẹ̀ jíjìn, níbi tí kò ti sí ilẹ̀ tí a lè dúró sí.+Mo ti dé inú omi tí ó jìn dòò,Àní ìṣàn ti gbá mi lọ.+
3 Ó ti rẹ̀ mí nítorí kíké tí mo ń ké jáde;+Ọ̀fun mi ti há.Ojú mi ti kọṣẹ́ bí mo ti ń dúró de Ọlọ́run mi.+
4 Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí tilẹ̀ ti wá pọ̀ ju irun orí mi lọ.+Àwọn tí ń pa mí lẹ́nu mọ́, tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá mi láìsí ìdí, ti di púpọ̀ níye.+Ohun tí n kò fi ìjanilólè gbà ni mo wá ń dá padà.
5 Ọlọ́run, ìwọ alára ti wá mọ ìwà òmùgọ̀ mi,Ẹ̀bi mi kò sì pa mọ́ kúrò lójú rẹ.+
6 Kí ojú má ti àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,+Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+Kí a má ṣe tẹ́ àwọn tí ń wá ọ lógo nítorí mi,+Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
7 Nítorí pé mo ti ru ẹ̀gàn ní tìtorí rẹ,+Ìtẹ́lógo ti bo ojú mi.+
8 Mo ti di ẹni tí àwọn arákùnrin mi kẹ̀yìn sí,+Mo sì ti di ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sí àwọn ọmọ ìyá mi.+
9 Nítorí pé ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run,+Àní ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ti ṣubú lù mí.+
10 Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà ọkàn mi,+Ṣùgbọ́n ó wá jẹ́ ẹ̀gàn fún mi.+
11 Nígbà tí mo fi aṣọ àpò ìdọ̀họ ṣe aṣọ mi,Mo wá di ẹni àfipòwe fún wọn.+
12 Àwọn tí ó jókòó sí ẹnubodè bẹ̀rẹ̀ sí fún ọ̀ràn mi ní àfiyèsí,+Èmi sì ni ẹṣin ọ̀rọ̀ orin àwọn tí ń mu ọtí tí ń pani.+
13 Ṣùgbọ́n ní tèmi, Jèhófà, ìwọ ni mo ń gba àdúrà sí,+Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, Ọlọ́run.+Nínú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, fi òtítọ́ ìgbàlà láti ọwọ́ rẹ dá mi lóhùn.+
14 Dá mi nídè kúrò nínú ẹrẹ̀, kí n má bàa rì.+Kí a dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi+ àti kúrò nínú omi jíjìn.+
15 Kí ìṣàn omi má ṣe gbá mi lọ,+Tàbí kí ibú gbé mi mì,Tàbí kí kànga pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.+
16 Dá mi lóhùn, Jèhófà, nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ dára.+Yí padà sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ògìdìgbó àánú rẹ,+
17 Má sì fi ojú rẹ pa mọ́ kúrò lára ìránṣẹ́ rẹ,+Nítorí tí mo wà nínú hílàhílo, tètè dá mi lóhùn.+
18 Sún mọ́ ọkàn mi, tún un gbà padà;+Tún mi rà padà ní tìtorí àwọn ọ̀tá mi.+
19 Ìwọ alára ti wá mọ ẹ̀gàn mi àti ìtìjú mi àti ìtẹ́lógo mi.+Gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi wà ní iwájú rẹ.+
20 Àní ẹ̀gàn ti ba ọkàn-àyà mi jẹ́, ọgbẹ́ náà sì jẹ́ aláìṣeéwòsàn.+Mo sì ń retí ṣáá láti rí ẹnì kan tí yóò fi ìbánikẹ́dùn hàn, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan;+Àti láti rí àwọn olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnì kankan.+
21 Ṣùgbọ́n wọ́n fún mi ní ọ̀gbìn onímájèlé láti fi ṣe oúnjẹ,+Àti fún òùngbẹ mi, wọ́n gbìyànjú láti mú mi mu ọtí kíkan.+
22 Jẹ́ kí tábìlì wọn tí ó wà níwájú wọn di pańpẹ́,+Kí ohun tí ó wà fún àlàáfíà wọn sì di ìdẹkùn.+
23 Jẹ́ kí ojú wọn di èyí tí ó ṣókùnkùn kí wọ́n má lè ríran;+Sì mú kí ìgbáròkó wọn pàápàá yẹ̀ nígbà gbogbo.+
24 Da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ wá sí wọn lórí,+Kí ìbínú rẹ jíjófòfò sì dé bá wọn.+
25 Jẹ́ kí ibùdó wọn tí a mọ ògiri yí ká di ahoro;+Kí ó má ṣe sí olùgbé kankan nínú àgọ́ wọn.+
26 Nítorí pé ẹni tí ìwọ tìkára rẹ kọlù ni wọ́n lépa,+Ìrora àwọn tí o gún sì ni wọ́n ń ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.
27 Fi ìṣìnà kún ìṣìnà wọn,+Kí wọ́n má sì wá sínú òdodo rẹ.+
28 Jẹ́ kí a nù wọ́n kúrò nínú ìwé àwọn alààyè,+Kí a má sì kọrúkọ wọn mọ́ àwọn olódodo.+
29 Ṣùgbọ́n a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́, ara sì ń ro mí.+Kí ìgbàlà rẹ dáàbò bò mí, Ọlọ́run.+
30 Ṣe ni èmi yóò máa fi orin yin orúkọ Ọlọ́run,+Èmi yóò sì fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.+
31 Èyí yóò sì wu Jèhófà ju akọ màlúù,+Ju ẹgbọrọ akọ màlúù tí ó ru ìwo sórí ṣaraṣara, èyí tí ó la pátákò.+
32 Àwọn ọlọ́kàn tútù yóò rí i dájúdájú; wọn yóò máa yọ̀.+Ẹ̀yin tí ń wá Ọlọ́run, kí ọkàn-àyà yín sì máa wà láàyè nìṣó.+
33 Nítorí tí Jèhófà ń fetí sí àwọn òtòṣì,+Ní tòótọ́, kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tirẹ̀.+
34 Kí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé máa yìn ín,+Àwọn òkun àti ohun gbogbo tí ń rìn kiri nínú wọn.+
35 Nítorí tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò gba Síónì là,+Yóò sì kọ́ àwọn ìlú ńlá Júdà;+Wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀ dájúdájú, àwọn ni yóò sì ni ín.+
36 Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni yóò sì jogún rẹ̀,+Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀ ni yóò sì máa gbé inú rẹ̀.+

