Sáàmù 64:1-10

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 64  Ọlọ́run, gbọ́ ohùn mi nínú ìdàníyàn mi.+Kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ ìwàláàyè mi lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo fún ọ̀tá.+   Kí o pa mí mọ́ lọ́wọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí àwọn aṣebi,+Lọ́wọ́ ìrúkèrúdò àwọn aṣenilọ́ṣẹ́,+   Àwọn tí ó ti pọ́n ahọ́n wọn gẹ́gẹ́ bí idà,+Àwọn tí ó ti fi ọfà wọn, tí í ṣe ọ̀rọ̀ kíkorò, sun ibi ìfojúsùn,+   Kí wọ́n lè ta aláìlẹ́bi lọ́fà láti àwọn ibi tí ó lùmọ́.+Wọ́n ta á lọ́fà lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.+   Wọ́n de ara wọn mọ́lẹ̀ sídìí ọ̀rọ̀ búburú;+Gbólóhùn tí wọ́n ń sọ jẹ́ nípa fífi pańpẹ́ pa mọ́.+Wọ́n wí pé: “Ta ni ó rí wọn?”+   Wọ́n ń wá àwọn ohun àìṣòdodo rí;+Wọ́n ti fi ohun àfọgbọ́nṣe tí wọ́n wá ní àwárí pa mọ́,+Apá inú olúkúlùkù, àní ọkàn-àyà rẹ̀, jìn.+   Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà lójijì.+Wọ́n ti gbọgbẹ́,+   Wọ́n sì mú kí ènìyàn kọsẹ̀.+Ṣùgbọ́n ahọ́n wọn dojú ìjà kọ àwọn fúnra wọn.+Gbogbo àwọn tí ń wò wọ́n yóò mi orí,+   Àyà yóò sì fo gbogbo ará ayé;+Wọn yóò sì máa sọ nípa ìgbòkègbodò Ọlọ́run,+Wọn yóò sì ní ìjìnlẹ̀ òye dájúdájú nípa iṣẹ́ rẹ̀.+ 10  Olódodo yóò sì máa yọ̀ nínú Jèhófà, yóò sì sá di í ní tòótọ́;+Gbogbo adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà yóò sì máa ṣògo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé