Sáàmù 63:1-11
Orin atunilára ti Dáfídì, nígbà tí ó wà ní aginjù Júdà.+
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, mo ń wá ọ ṣáá.+Òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.+Àárẹ̀ ti mú ẹran ara mi nítorí ìyánhànhàn fún ọNí ilẹ̀ tí ó gbẹ tí ó sì rí táútáú, níbi tí omi kò sí.+
2 Bí mo ṣe rí ọ nìyẹn nínú ibi mímọ́,+Nígbà tí mo rí okun rẹ àti ògo rẹ.+
3 Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè,+Ètè mi yóò gbóríyìn fún ọ.+
4 Bí èmi yóò ṣe máa fi ìbùkún fún ọ nìyẹn ní ìgbà ayé mi;+Èmi yóò máa gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè ní orúkọ rẹ.+
5 Bí ẹni pé pẹ̀lú apá tí ó dára jù lọ, àní ọ̀rá, ọkàn mi ni a tẹ́ lọ́rùn,+Ètè tí ó kún fún igbe ìdùnnú sì ni ẹnu mi fi ń mú ìyìn wá.+
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi,+Mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru.+
7 Nítorí pé ìwọ ti já sí ìrànwọ́ fún mi,+Mo sì ń fi ìdùnnú ké jáde nínú òjìji ìyẹ́ apá rẹ.+
8 Ọkàn mi ti tẹ̀ lé ọ pẹ́kípẹ́kí;+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ dì mí mú ṣinṣin.+
9 Ní ti àwọn tí ń wá ọkàn mi ṣáá láti pa á run,+Wọn yóò wá sí ibi rírẹlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé.+
10 A ó fà wọ́n lé agbára idà lọ́wọ́;+Wọn yóò di ìpín lásán-làsàn fún àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.+
11 Ọba tìkára rẹ̀ yóò sì máa yọ̀ nínú Ọlọ́run.+Olúkúlùkù ẹni tí ń fi í búra yóò máa ṣògo,+Nítorí pé ẹnu àwọn tí ń ṣèké ni a óò mú dákẹ́ fẹ́mú.+

