Sáàmù 62:1-12
Sí olùdarí Jédútúnì. Orin atunilára ti Dáfídì.
62 Ní tòótọ́, Ọlọ́run ni ọkàn mi ń dúró dè ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.+Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni ìgbàlà mi.+
2 Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi;+A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n púpọ̀ jù.+
3 Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa bá a lọ ní ṣíṣe kìtàkìtà sí ẹni tí ẹ ó ṣìkà pa?+Gbogbo yín dà bí ògiri títẹ̀, ògiri òkúta tí ń tẹ̀ wọnú lọ.+
4 Ní tòótọ́, wọ́n ń fúnni ní àmọ̀ràn láti lè dẹni lọ kúrò nínú iyì ẹni;+Wọ́n ní ìdùnnú nínú irọ́.+Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n nínú, wọ́n ń pe ibi wá síni lórí.+ Sélà.
5 Ní tòótọ́, fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de Ọlọ́run, ìwọ ọkàn mi,+Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.+
6 Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi;+A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+
7 Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi àti ògo mi wà.+Àpáta lílágbára mi, ibi ìsádi mi wà nínú Ọlọ́run.+
8 Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà.+Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀.+Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.+ Sélà.
9 Ní tòótọ́, èémí àmíjáde ni àwọn ọmọ ará ayé,+Irọ́ ni àwọn ọmọ aráyé.+Nígbà tí a bá gbé wọn lé òṣùwọ̀n, gbogbo wọn lápapọ̀ fúyẹ́ ju èémí àmíjáde.+
10 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì lílù,+Tàbí kí ẹ di asán nínú olè jíjà paraku.+Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà ń gbèrú, ẹ má ṣe gbé ọkàn-àyà yín lé e.+
11 Ẹ̀ẹ̀kan ni Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀, ẹ̀ẹ̀mejì sì ni mo ti gbọ́ èyí pàápàá,+Pé ti Ọlọ́run ni okun.+
12 Pẹ̀lúpẹ̀lù, tìrẹ ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́, Jèhófà,+Nítorí tí ìwọ tìkára rẹ ń san án padà fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.+

