Sáàmù 61:1-8
Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Ti Dáfídì.
61 Gbọ́ igbe ìpàrọwà mi, Ọlọ́run.+Fetí sí àdúrà mi.+
2 Èmi yóò kígbe láti ìkángun ilẹ̀ ayé, àní sí ọ, nígbà tí ọkàn-àyà mi bá di ahẹrẹpẹ.+Kí o ṣamọ̀nà mi lọ sórí àpáta tí ó ga jù mí.+
3 Nítorí pé o ti jẹ́ ibi ìsádi fún mi,+Ilé gogoro lílágbára ní ojú ọ̀tá.+
4 Dájúdájú, èmi yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin;+Èmi yóò sá di ibi ìlùmọ́ ìyẹ́ apá rẹ.+ Sélà.
5 Nítorí pé ìwọ fúnra rẹ, Ọlọ́run, ti fetí sí àwọn ẹ̀jẹ́ mi.+O ti fún mi ní ohun ìní àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.+
6 Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ìwọ yóò fi kún àwọn ọjọ́ ọba;+Àwọn ọdún rẹ̀ yóò dà bí ìran dé ìran.+
7 Òun yóò máa gbé fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú Ọlọ́run;+Fún un ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́, kí ìwọ̀nyí lè máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.+
8 Ó dájú pé báyìí ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ títí láé,+Kí n lè san àwọn ẹ̀jẹ́ mi ní ọjọ́ dé ọjọ́.+

