Sáàmù 6:1-10

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín lórí ọ́kítéfì ìsàlẹ̀.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 6  Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,+Má sì ṣe tọ́ mi sọ́nà nínú ìhónú rẹ.+  2  Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà, nítorí pé okun mi ń tán lọ.+Mú mi lára dá,+ Jèhófà, nítorí pé a ti yọ egungun mi lẹ́nu.  3  Bẹ́ẹ̀ ni, a ti yọ ọkàn mi lẹ́nu gidigidi;+Àti ìwọ, Jèhófà—yóò ti pẹ́ tó?+  4  Padà,+ Jèhófà, gba ọkàn mi sílẹ̀;+Gbà mí là nítorí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+  5  Nítorí tí kò sí mímẹ́nukàn ọ́ nínú ikú;+Nínú Ṣìọ́ọ̀lù, ta ni yóò gbé ọ lárugẹ?+  6  Agara ìmí ẹ̀dùn mi ti dá mi;+Láti òru mọ́jú ni mo ń mú kí àga ìrọ̀gbọ̀kú mi rin gbingbin;+Omijé mi ni mo fi ń mú kí àga ìnàyìn mi kún àkúnwọ́sílẹ̀.+  7  Ìbìnújẹ́ ti sọ ojú mi di aláìlera,+Ó ti di ogbó nítorí gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi.+  8  Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin aṣenilọ́ṣẹ́,+Nítorí pé Jèhófà yóò gbọ́ ìró ẹkún mi dájúdájú.+  9  Ní tòótọ́, Jèhófà yóò gbọ́ ìbéèrè mi fún ojú rere;+Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gba àdúrà tèmi.+ 10  Ojú yóò ti+ gbogbo àwọn ọ̀tá mi, a ó sì yọ wọ́n lẹ́nu gan-an;Wọn yóò yí padà, ojú yóò tì wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé