Sáàmù 58:1-11
Sí olùdarí. “Má ṣe run ún.” Ti Dáfídì. Míkítámù.
58 Nínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́ yín, ẹ ha lè sọ̀rọ̀ nípa òdodo ní ti tòótọ́ bí?+Ẹ ha lè ṣe ìdájọ́ nínú ìdúróṣánṣán bí, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn?+
2 Kàkà bẹ́ẹ̀, mélòómélòó ni ẹ ń fi ọkàn-àyà ṣe àìṣòdodo paraku ní ilẹ̀ ayé,+Tí ẹ sì ń palẹ̀ ọ̀nà mọ́, àní fún ìwà ipá ọwọ́ yín!+
3 Àwọn ẹni burúkú ti jẹ́ aláyìídáyidà láti inú ilé ọlẹ̀ wá;+Láti ìgbà tí wọ́n ti wà nínú ikùn ni wọ́n ti ń rìn gbéregbère;Wọ́n ń purọ́.+
4 Oró wọ́n dà bí oró ejò,+Wọ́n jẹ́ adití bí ṣèbé tí ń di etí rẹ̀,+
5 Tí kì í fetí sí ohùn àwọn atujú,+Bí ẹni tí ó gbọ́n tilẹ̀ ń lo èèdì.+
6 Ọlọ́run, gbá eyín wọn yọ lẹ́nu wọn.+Àní kí o fọ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ túútúú, Jèhófà.
7 Kí wọ́n yọ́ bí ẹni pé sínú omi tí ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ;+Kí ó fa ọrun fún àwọn ọfà rẹ̀ bí wọ́n ti ń wó lulẹ̀.+
8 Ó ń rìn bí ìgbín tí ń yọ́ dànù;Bí ìṣẹ́nú obìnrin, ó dájú pé wọn kì yóò rí oòrùn.+
9 Kí àwọn ìkòkò yín tó mọ igi ẹlẹ́gún+ tí ń jó lára,Ààyè ewéko àti èyí tí ń jó, òun yóò gbé wọn lọ bí ẹ̀fúùfù oníjì.+
10 Olódodo yóò máa yọ̀ nítorí pé ó ti rí ẹ̀san.+Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹni burúkú wẹ àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀.+
11 Aráyé yóò sì sọ pé:+ “Dájúdájú, èso ń bẹ fún olódodo.+Dájúdájú, Ọlọ́run kan wà tí ń ṣe ìdájọ́ ní ilẹ̀ ayé.”+

