Sáàmù 57:1-11
Sí olùdarí. “Má ṣe run ún.” Ti Dáfídì. Míkítámù. Nígbà tí ó fẹsẹ̀ fẹ nítorí Sọ́ọ̀lù, tí ó sì lọ sínú hòrò.+
57 Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, fi ojú rere hàn sí mi,+Nítorí pé ìwọ ni ọkàn mi sá di;+Òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni mo sá di títí àwọn àgbákò fi ré kọjá.+
2 Mo ké pe Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ, mo ké pe Ọlọ́run tòótọ́ tí ń mú wọn wá sí òpin ní tìtorí mi.+
3 Yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí là.+Dájúdájú, òun yóò kó ìdàrúdàpọ̀ bá ẹni tí ń kù gìrì mọ́ mi.+ Sélà.Ọlọ́run yóò fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ̀ ránṣẹ́.+
4 Ọkàn mi wà ní àárín àwọn kìnnìún;+Èmi kò lè ṣàìdùbúlẹ̀ sáàárín àwọn ajẹnirun, àní àwọn ọmọ ènìyàn,Àwọn tí eyín wọ́n jẹ́ ọ̀kọ̀ àti ọfà,+Tí ahọ́n wọ́n sì jẹ́ idà mímú.+
5 Kí a gbé ọ ga lékè ọ̀run, Ọlọ́run;+Kí ògo rẹ wà lókè gbogbo ilẹ̀ ayé.+
6 Àwọ̀n ni wọ́n ti dẹ sílẹ̀ de àwọn ìṣísẹ̀ mi;+Ọkàn mi ti tẹ̀ ba.+Wọ́n wa ọ̀fìn síwájú mi;Wọ́n ti jìn sí àárín rẹ̀.+ Sélà.
7 Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run,+Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.Ṣe ni èmi yóò máa kọrin, tí èmi yóò sì máa kọ orin atunilára.+
8 Jí, ìwọ ògo mi;+Jí, ìwọ ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù,+Ṣe ni èmi yóò jí ọ̀yẹ̀.
9 Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ láàárín àwọn ènìyàn, Jèhófà;+Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí ọ láàárín àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.+
10 Nítorí tí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ga títí dé ọ̀run,+Àti òótọ́ rẹ títí dé sánmà.+
11 Kí a gbé ọ ga lékè ọ̀run, Ọlọ́run;+Kí ògo rẹ wà lókè gbogbo ilẹ̀ ayé.

