Sáàmù 52:1-9
Sí olùdarí. Másíkílì. Ti Dáfídì, nígbà tí Dóẹ́gì ọmọ Édómù wá, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sọ́ọ̀lù, tí ó sì wí fún un pé Dáfídì wá sí ilé Áhímélékì.+
52 Èé ṣe tí ìwọ ń fi ohun búburú ṣògo, ìwọ alágbára ńlá?+Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run wà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+
2 Àgbákò ni ahọ́n rẹ ń pète-pèrò, a pọ́n ọn bí abẹ fẹ́lẹ́,+Ó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn.+
3 Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ohun búburú ju ohun rere,+Ìwọ nífẹ̀ẹ́ èké ju sísọ òdodo.+ Sélà.
4 Ìwọ nífẹ̀ẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ń jẹni run,+Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn.+
5 Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò sì bì ọ́ wó títí láé;+Òun yóò là ọ́ mọ́lẹ̀, yóò sì ya ọ́ kúrò nínú àgọ́ rẹ,+Dájúdájú, òun yóò fà ọ́ tu kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè.+ Sélà.
6 Àwọn olódodo yóò sì rí i, àyà yóò sì fò wọ́n,+Wọn yóò sì máa fi í rẹ́rìn-ín.+
7 Abarapá ọkùnrin tí kò fi Ọlọ́run ṣe odi agbára rẹ̀ rèé,+Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀ rẹ̀,+Tí ó ń fi àgbákò láti ọwọ́ rẹ̀ ṣe ibi ààbò.+
8 Ṣùgbọ́n èmi yóò rí bí igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ nínú ilé Ọlọ́run;Mo gbẹ́kẹ̀ lé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+
9 Ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí pé ìwọ ti gbé ìgbésẹ̀;+Èmi yóò sì ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí tí ó dára, ní iwájú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ.+

