Sáàmù 50:1-23
Orin atunilára ti Ásáfù.+
50 Olú Ọ̀run,+ Ọlọ́run, Jèhófà,+ ti fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀,+Ó sì tẹ̀ síwájú láti pe ilẹ̀ ayé,+Láti yíyọ oòrùn títí di wíwọ̀ rẹ̀.+
2 Láti Síónì, tí í ṣe ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra,+ ni Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti tàn yanran jáde.+
3 Ọlọ́run wa yóò wá, kò sì ṣeé ṣe pé kí ó dákẹ́.+Iná ń jẹ run níwájú rẹ̀,+Ní gbogbo àyíká rẹ̀, ojú ọjọ́ ti di oníjì lọ́nà tí ó peléke.+
4 Ó ké pe ọ̀run lókè, ó sì ké pe ilẹ̀ ayé+Láti lè mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí àwọn ènìyàn rẹ̀+ pé:
5 “Ẹ kó àwọn ẹni ìdúróṣinṣin mi jọ sọ́dọ̀ mi,+Àwọn tí ó dá májẹ̀mú mi lórí ẹbọ.”+
6 Àwọn ọ̀run sì ń sọ nípa òdodo rẹ̀,+Nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Onídàájọ́.+ Sélà.
7 “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yóò sọ̀rọ̀,+Ìwọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì jẹ́rìí lòdì sí ọ.+Èmi ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.+
8 Èmi kò bá ọ wí nípa àwọn ẹbọ rẹ,+Tàbí nípa àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ tí ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo.+
9 Dájúdájú, èmi kì yóò mú akọ màlúù kan nínú ilé rẹ,+Àti àwọn òbúkọ nínú ọgbà ẹran rẹ.
10 Nítorí pé tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó,+Àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá.+
11 Èmi mọ olúkúlùkù ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń bẹ lórí àwọn òkè ńlá ní àmọ̀dunjú,+Ògídímèje àwọn ẹran pápá gbalasa sì ń bẹ pẹ̀lú mi.+
12 Ká ní ebi ń pa mí ni, èmi kò ní sọ fún ọ;Nítorí pé tèmi ni ilẹ̀ eléso+ àti ẹ̀kún rẹ̀.+
13 Èmi yóò ha jẹ ẹran àwọn akọ màlúù lílágbára,+Èmi yóò ha sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn òbúkọ bí?+
14 Rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ sí Ọlọ́run,+Kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ;+
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ wàhálà.+Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀, ìwọ yóò sì máa yìn mí lógo.”+
16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò sọ fún ẹni burúkú pé:+“Ẹ̀tọ́ wo ni ìwọ ní láti máa ka àwọn ìlànà mi lẹ́sẹẹsẹ,+Tí ìwọ yóò sì máa sọ̀rọ̀ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?+
17 Họ́wù, ìwọ—ìwọ kórìíra ìbáwí,+Ìwọ sì ń ju ọ̀rọ̀ mi sẹ́yìn rẹ.+
18 Nígbàkigbà tí o bá rí olè, inú rẹ tilẹ̀ ń dùn sí i;+Ìpín rẹ sì ń bẹ pẹ̀lú àwọn panṣágà.+
19 Ìwọ ti la ẹnu rẹ gbùà sí ohun búburú,+O sì so ahọ́n rẹ mọ́ ẹ̀tàn.+
20 Ìwọ jókòó, ìwọ sì sọ̀rọ̀ lòdì sí arákùnrin tìrẹ,+Ìwọ sì gbé àléébù ọmọ ìyá rẹ sáyé.+
21 Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ṣe, mo sì dákẹ́.+Ìwọ lérò pé ó dájú hán-ún pé èmi yóò dà bí tìrẹ.+Èmi yóò fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà,+ dájúdájú, èmi yóò mú àwọn nǹkan tọ́ ní ìṣojú rẹ.+
22 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lóye èyí, ẹ̀yin tí ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run,+Kí n má bàa fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí olùdáǹdè kankan.+
23 Ẹni tí ń rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀ ni ó ń yìn mí lógo;+Àti ní ti ẹni tí ń pa ọ̀nà tí a là sílẹ̀ mọ́,Dájúdájú, èmi yóò jẹ́ kí ó rí ìgbàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run.”+

