Sáàmù 5:1-12

Sí olùdarí fún Néhílótì. Orin atunilára ti Dáfídì. 5  Fi etí sí àwọn àsọjáde mi,+ Jèhófà;Lóye ìmí ẹ̀dùn mi.  2  Fetí sí ìró igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,+Ìwọ Ọba+ mi àti Ọlọ́run mi, nítorí pé ìwọ ni mo ń gbàdúrà sí.+  3  Jèhófà, ní òwúrọ̀, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;+Ní òwúrọ̀, èmi yóò darí àfiyèsí mi sọ́dọ̀ rẹ, èmi yóò sì máa ṣọ́nà.+  4  Nítorí pé ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ń ní inú dídùn sí ìwà burúkú;+Kò sí ẹni búburú tí ó lè bá ọ gbé fún ìgbà èyíkéyìí.+  5  Kò sí àwọn aṣògo tí ó lè mú ìdúró wọn ní iwájú rẹ.+Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́;+  6  Ìwọ yóò pa àwọn tí ń purọ́ run.+Ẹni ìtàjẹ̀sílẹ̀+ àti ẹni ẹ̀tàn+ ni Jèhófà ń ṣe họ́ọ̀ sí.  7  Ní tèmi, èmi yóò wá sínú ilé rẹ+Nínú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+Èmi yóò tẹrí ba síhà tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ nínú ẹ̀rù rẹ.+  8  Jèhófà, ṣamọ̀nà mi nínú òdodo rẹ+ nítorí àwọn ọ̀tá mi;+Mú ọ̀nà rẹ tẹ́jú níwájú mi.+  9  Nítorí tí kò sí nǹkan kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ní ẹnu wọn;+Àgbákò gidi ni ìhà inú wọn.+Ibi ìsìnkú tí ó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;+Ahọ́n dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in ni wọ́n ń lò.+ 10  Dájúdájú, Ọlọ́run yóò kà wọ́n sí ẹlẹ́bi;+Wọn yóò ṣubú nítorí àwọn ìmọ̀ràn tiwọn.+Nínú ògìdìgbó ìrélànàkọjá wọn, kí wọ́n di fífọ́nká.+Nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.+ 11  Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ń sá di ọ́ yóò máa yọ̀;+Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde.+Ìwọ yóò sì dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ wọn,Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú rẹ.+ 12  Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, yóò bù kún olódodo;+Ìtẹ́wọ́gbà ni ìwọ yóò fi yí wọn ká+ bí apata ńlá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé