Sáàmù 49:1-20
Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin atunilára.
49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn.Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin olùgbé inú ètò àwọn nǹkan,+
2 Ẹ̀yin ọmọ ìran ènìyàn àti ẹ̀yin ọmọ ènìyàn,Ìwọ ọlọ́rọ̀ àti ìwọ òtòṣì lápapọ̀.+
3 Ẹnu mi yóò sọ àwọn ohun ọgbọ́n,+Àṣàrò inú ọkàn-àyà mi yóò sì jẹ́ ti àwọn ohun òye.+
4 Èmi yóò dẹ etí mi sí gbólóhùn òwe;+Háàpù ni èmi yóò fi pa àlọ́ mi.+
5 Èé ṣe tí èmi yóò fi máa fòyà ní àwọn ọjọ́ ibi,+Nígbà tí àwọn ìṣìnà olùfèrúgbapò mi yí mi ká?+
6 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà ara wọn,+Tí wọ́n sì ń ṣògo nípa ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀ wọn,+
7 Kò sí ẹnì kankan nínú wọn tí ó lè tún arákùnrin kan pàápàá rà padà+ ní ọ̀nà èyíkéyìí,Tàbí kí ó fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀;
8 (Iye owó ìtúnràpadà ọkàn wọn ṣe iyebíye+ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́Tí ó fi jẹ́ pé ó ti kásẹ̀ nílẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin)
9 Tí yóò ṣì fi wà láàyè títí láé, kí ó má sì rí kòtò.+
10 Nítorí ó ń rí i pé àwọn ọlọ́gbọ́n pàápàá ń kú,+Arìndìn àti ẹni tí kì í ronú jọ ń ṣègbé,+Wọn yóò sì fi àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn sílẹ̀ fún àwọn mìíràn.+
11 Ìdàníyàn wọn àtinúwá ni pé kí ilé wọn lè wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Kí àgọ́ wọn wà láti ìran dé ìran.+Wọ́n fi orúkọ wọn pe àwọn ilẹ̀ ìní wọn.+
12 Síbẹ̀síbẹ̀, ará ayé, bí ó tilẹ̀ wà nínú ọlá, kò lè máa wà nìṣó;+Ní tòótọ́, ó ṣée fi wé àwọn ẹranko tí a ti pa run.+
13 Èyí ni ọ̀nà àwọn tí ó ya dìndìnrìn,+Àti ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn, tí ó ní ìdùnnú sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Sélà.
14 Bí àgùntàn, a ti yàn wọ́n kalẹ̀ fún Ṣìọ́ọ̀lù;+Ikú ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn;+Àwọn adúróṣánṣán yóò sì jọba lé wọn lórí ní òwúrọ̀,+Ìrísí wọn yóò sì ṣá;+Ṣìọ́ọ̀lù, dípò ibùjókòó gíga fíofío, ní ń bẹ fún olúkúlùkù wọn.+
15 Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò tún ọkàn mi rà padà kúrò ní ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù,+Nítorí òun yóò gbà mí. Sélà.
16 Má fòyà nítorí pé ẹnì kan ń jèrè ọrọ̀,+Nítorí pé ògo ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i,+
17 Nítorí pé nígbà ikú rẹ̀, kò lè mú nǹkan kan dání rárá;+Ògo rẹ̀ kì yóò bá òun alára sọ̀ kalẹ̀.+
18 Nítorí pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó ń súre fún ọkàn ara rẹ̀;+(Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbé ọ lárugẹ nítorí tí ìwọ ń ṣe rere fún ara rẹ)+
19 Nígbẹ̀yìn, kìkì ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba ńlá rẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ dé.+Wọn kì yóò rí ìmọ́lẹ̀ mọ́ láé.+
20 Ará ayé tí kò lóye, bí ó tilẹ̀ wà nínú ọlá,+Ní tòótọ́, ṣeé fi wé àwọn ẹranko tí a ti pa run.+

