Sáàmù 47:1-9

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà. Orin atunilára. 47  Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, ẹ pàtẹ́wọ́.+Ẹ fi ìró igbe ìdùnnú kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run.+   Nítorí pé Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ, jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù,+Ọba ńlá lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.+   Òun yóò tẹ àwọn ènìyàn ba lábẹ́ wa+Àti àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè lábẹ́ ẹsẹ̀ wa.+   Òun yóò yan ogún wa fún wa,+Ohun ìyangàn Jékọ́bù, ẹni tí òun nífẹ̀ẹ́.+ Sélà.   Ọlọ́run ti gòkè tòun ti igbe ìdùnnú,+Jèhófà tòun ti ìró ìwo.+   Ẹ kọ orin atunilára sí Ọlọ́run, ẹ kọ orin atunilára.+Ẹ kọ orin atunilára sí Ọba wa, ẹ kọ orin atunilára.   Nítorí pé Ọlọ́run ni Ọba gbogbo ilẹ̀ ayé;+Ẹ kọ orin atunilára, ní fífi ọgbọ́n inú hùwà.+   Ọlọ́run ti di ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.+Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti mú ìjókòó lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.+   Àní àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú àwọn ènìyàn ti kóra jọpọ̀,+Pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run Ábúráhámù.+Nítorí pé ti Ọlọ́run ni àwọn apata ilẹ̀ ayé.+Ó ròkè gan-an dé ipò gíga.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé