Sáàmù 46:1-11
Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà+ lórí Àwọn Omidan. Orin.
46 Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa,+Ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.+
2 Ìdí nìyẹn tí àwa kì yóò bẹ̀rù, bí ilẹ̀ ayé tilẹ̀ yí padà,+Bí àwọn òkè ńláńlá tilẹ̀ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n wọ àárín alagbalúgbú òkun;+
3 Bí omi rẹ̀ tilẹ̀ di aláriwo líle, tí ó ń yọ ìfófòó sókè,+Bí àwọn òkè ńláńlá tilẹ̀ mì jìgìjìgì nítorí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ rẹ̀.+ Sélà.
4 Odò kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ ń mú kí ìlú ńlá Ọlọ́run máa yọ̀,+Atóbilọ́lá àgọ́ ìjọsìn mímọ́ jù lọ ti Ẹni Gíga Jù Lọ.+
5 Ọlọ́run ń bẹ ní àárín ìlú ńlá náà;+ a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ nígbà tí òwúrọ̀ bá fara hàn.+
6 Àwọn orílẹ̀-èdè di aláriwo líle,+ àwọn ìjọba ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n;Ó fọ ohùn rẹ̀, ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí yọ́.+
7 Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ ibi gíga ààbò fún wa.+ Sélà.
8 Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà,+Bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.+
9 Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.+Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́;+Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.+
10 “Ẹ juwọ́ sílẹ̀, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.+Dájúdájú, a óò gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+A óò gbé mi ga ní ilẹ̀ ayé.”+
11 Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ ibi gíga ààbò fún wa.+ Sélà.

