Sáàmù 45:1-17

Sí olùdarí lórí Òdòdó Lílì. Ti àwọn ọmọ Kórà. Másíkílì. Orin nípa àwọn obìnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n. 45  Ọkàn-àyà mi ti gbé fúkẹ́ nípa ọ̀ràn kan tí ó jọjú.+Èmi ń sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ mi jẹ́ nípa ọba kan.”+Kí ahọ́n mi jẹ́ kálàmù+ ọ̀jáfáfá adàwékọ.+  2  Ní tòótọ́, ìwọ rẹwà ju àwọn ọmọ ènìyàn.+A ti da òòfà ẹwà sí ètè rẹ.+Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi bù kún ọ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  3  Sán idà rẹ+ mọ́ itan rẹ, ìwọ alágbára ńlá,+Pẹ̀lú iyì rẹ àti ọlá ńlá rẹ.+  4  Àti nínú ọlá ńlá rẹ, kí o tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere;+Máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì máa fún ọ ní ìtọ́ni nínú àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù.+  5  Àwọn ọfà rẹ mú—àwọn ènìyàn ń ṣubú lábẹ́ rẹ+—Ní ọkàn-àyà àwọn ọ̀tá ọba.+  6  Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé;+Ọ̀pá aládé àkóso rẹ jẹ́ ọ̀pá aládé ìdúróṣánṣán.+  7  Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo,+ o sì kórìíra ìwà burúkú.+Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ,+ fi fòróró+ ayọ̀ ńláǹlà+ yàn ọ́ ju àwọn alájọṣe+ rẹ.  8  Òjíá àti álóè àti kasíà+ ni gbogbo ẹ̀wù rẹ;Láti inú ààfin títóbi lọ́lá tí a fi eyín erin+ ṣe ni àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín ti ń mú ọ yọ̀.  9  Àwọn ọmọbìnrin+ àwọn ọba wà lára àwọn obìnrin rẹ tí ó ṣe iyebíye.Olorì+ ti mú ìdúró rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ nínú wúrà Ófírì.+ 10  Fetí sílẹ̀, ìwọ ọmọbìnrin, kí o sì wò, kí o sì dẹ etí rẹ sílẹ̀;Kí o sì gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.+ 11  Ọba yóò sì máa yánhànhàn fún ẹwà rẹ tí ó fani mọ́ra,+Nítorí òun ni olúwa rẹ,+Nítorí náà, tẹrí ba fún un.+ 12  Ọmọbìnrin Tírè tòun ti ẹ̀bùn+—Àwọn ọlọ́rọ̀ lára àwọn ènìyàn yóò tù ọ́ lójú.+ 13  Ọmọbìnrin ọba kún fún ògo látòkè délẹ̀ láàárín ilé;+Aṣọ rẹ̀ ní àwọn ibi tí a lẹ wúrà mọ́. 14  Nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ híhun ni a óò mú un tọ ọba wá.+Àwọn wúńdíá tí ó wà nínú ẹgbẹ́ abánirìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni a óò mú tọ ìwọ wá.+ 15  A óò mú wọn wá pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú;Wọn yóò wọ ààfin ọba. 16  Ní ipò àwọn baba ńlá+ rẹ ni àwọn ọmọkùnrin+ rẹ yóò wà,Àwọn tí ìwọ yóò yàn ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 17  Ṣe ni èmi yóò máa mẹ́nu kan orúkọ rẹ jálẹ̀ gbogbo ìran tí ń bọ̀.+Ìdí nìyẹn tí àwọn ènìyàn tìkára wọn yóò máa gbé ọ lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé