Sáàmù 43:1-5

43  Ṣe ìdájọ́ mi,+ Ọlọ́run,Kí o sì bá mi dá ẹjọ́ mi+ lòdì sí orílẹ̀-èdè tí kò dúró ṣinṣin.Kí o pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti aláìṣòdodo.+   Nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run odi agbára mi.+Èé ṣe tí o fi ta mí nù?Èé ṣe tí mo fi ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́ nítorí ìnilára láti ọwọ́ ọ̀tá?+   Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.+Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.+Kí wọ́n mú mi wá sí òkè ńlá mímọ́ rẹ àti sí àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá.+   Dájúdájú, èmi yóò wá síbi pẹpẹ Ọlọ́run,+Sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ayọ̀ yíyọ̀ mi tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà.+Èmi yóò sì fi háàpù gbé ọ lárugẹ, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run mi.+   Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi,+Èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi?Dúró de Ọlọ́run,+Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára àti gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé