Sáàmù 42:1-11
Sí olùdarí. Másíkílì fún àwọn ọmọ Kórà.+
42 Bí egbin tí ń yánhànhàn fún ìṣàn omi,Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi gan-an ń yánhànhàn fún ọ, Ọlọ́run.+
2 Òùngbẹ Ọlọ́run,+ àní Ọlọ́run alààyè,+ ń gbẹ ọkàn mi ní tòótọ́,Ìgbà wo ni èmi yóò wá, tí èmi yóò sì fara hàn níwájú Ọlọ́run?+
3 Omijé mi ti di oúnjẹ mi ní ọ̀sán àti ní òru,+Bí wọ́n ti ń sọ fún mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+
4 Nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò rántí, èmi yóò sì tú ọkàn mi jáde nínú mi.+Nítorí pé mo ti máa ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn kọjá lọ tẹ́lẹ̀ rí,Mo ti máa ń rọra rìn níwájú wọn lọ sí ilé Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí,+Pẹ̀lú ohùn igbe ìdùnnú àti ìdúpẹ́,+Ti ogunlọ́gọ̀ tí ń ṣe àjọyọ̀.+
5 Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi,+Èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi?+Dúró de Ọlọ́run,+Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára.+
6 Ìwọ Ọlọ́run mi, àní ọkàn mi ń bọ́hùn nínú mi.+Ìdí nìyẹn tí mo fi rántí rẹ,+Láti ilẹ̀ Jọ́dánì àti àwọn téńté Hámónì,+Láti òkè ńlá tí kò fi bẹ́ẹ̀ ga.+
7 Ibú omi ń ké sí ibú omiNípa ìró àwọn ìdàṣọ̀ọ̀rọ̀ (omi) rẹ.Gbogbo ìrugùdù omi rẹ tí ń fọ́n ká di ìfóófòó àti ìgbì rẹ+—Wọ́n ti kọjá lórí mi.+
8 Ní ọ̀sán, Jèhófà yóò pàṣẹ inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́,+Àti ní òru, orin rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú mi;+Àdúrà yóò wà sí Ọlọ́run ìwàláàyè mi.+
9 Dájúdájú, èmi yóò wí fún Ọlọ́run àpáta gàǹgà mi pé:+“Èé ṣe tí o fi gbàgbé mi?+Èé ṣe tí mo fi ń rìn nínú ìbànújẹ́ nítorí ìnilára ọ̀tá?”+
10 Àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi ti dá ọgbẹ́ tí ń ṣekú pani sí egungun mi láti gàn mí,+Bí wọ́n ti ń sọ fún mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+
11 Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi,+Èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi?+Dúró de Ọlọ́run,+Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára àti gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mi.+