Sáàmù 40:1-17
Sí olùdarí. Ti Dáfídì, orin atunilára.
40 Taratara ni mo fi ní ìrètí nínú Jèhófà,+Nítorí náà, ó dẹ etí rẹ̀ sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+
2 Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi gòkè pẹ̀lú láti inú kòtò tí ń ké ramúramù,+Láti inú ẹrẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀.+Nígbà náà ni ó gbé ẹsẹ̀ mi sókè sórí àpáta gàǹgà;+Ó fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+
3 Síwájú sí i, ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,Ìyìn sí Ọlọ́run wa.+Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò rí i, wọn yóò sì bẹ̀rù,+Wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+
4 Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀+Tí kò sì yíjú sí àwọn aṣàyàgbàǹgbà-peni-níjà,Tàbí sí àwọn tí ń yà sínú irọ́.+
5 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe,+Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa;+Kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.+Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni,Wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.+
6 Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò ní inú dídùn sí;+Etí tèmi yìí ni ìwọ là sílẹ̀.+Ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè.+
7 Nítorí èyí, mo wí pé: “Kíyè sí i, mo ti dé,+Nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi.+
8 Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí,+Òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.+
9 Mo ti sọ ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá.+Wò ó! Èmi kò ṣèdíwọ́ fún ètè mi.+Jèhófà, ìwọ alára mọ ìyẹn ní àmọ̀dunjú.+
10 Èmi kò bo òdodo rẹ mọ́lẹ̀ ní ọkàn-àyà mi.+Mo ti polongo ìṣòtítọ́ rẹ àti ìgbàlà rẹ.+Èmi kò fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ pa mọ́ nínú ìjọ ńlá.”+
11 Ìwọ alára, Jèhófà, má fa ojú àánú rẹ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.+Jẹ́ kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ máa fi ìṣọ́ ṣọ́ mi nígbà gbogbo.+
12 Nítorí pé àwọn ìyọnu àjálù ká mi mọ́ títí iye wọn kò fi ṣeé kà.+Ọ̀pọ̀ ìṣìnà tèmi lé mi bá ju bí mo ti lè rí i;+Wọ́n pọ̀ níye ju irun orí mi,+Ọkàn-àyà mi sì fi mí sílẹ̀.+
13 Kí ó dùn mọ́ ọ nínú, Jèhófà, láti dá mi nídè.+Jèhófà, ṣe kánkán láti wá ṣe ìrànwọ́ fún mi.+
14 Kí ojú tì wọ́n, kí gbogbo wọn sì tẹ́ pa pọ̀,+Àwọn tí ń wá ọkàn mi láti gbá a lọ.+Kí wọ́n yí padà, kí a sì tẹ́ wọn lógo, àwọn tí ó ní inú dídùn sí ìyọnu àjálù mi.+
15 Kí wọ́n máa wò sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì nítorí ìtìjú wọn,+Àwọn tí ń wí fún mi pé: “Àháà! Àháà!”+
16 Kí wọ́n máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí wọ́n sì máa yọ̀ nínú rẹ,+Gbogbo àwọn tí ń wá ọ.+Kí wọ́n máa wí nígbà gbogbo pé: “Kí Jèhófà di àgbégalọ́lá,”+Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ ìgbàlà tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ wá.+
17 Ṣùgbọ́n ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí.+Jèhófà tìkára rẹ̀ ń gba tèmi rò.+Ìwọ ni ìrànwọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.+Ìwọ Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ jù.+

