Sáàmù 4:1-8

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 4  Nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn, ìwọ Ọlọ́run mi olódodo.+Nínú wàhálà, kí ó ṣe àyè fífẹ̀ fún mi.Fi ojú rere hàn sí mi,+ kí o sì gbọ́ àdúrà mi.   Ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, yóò ti pẹ́ tó tí ògo mi+ yóò fi jẹ́ fún ìwọ̀sí,Nígbà tí ẹ ń nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan òfìfo,Nígbà tí ẹ ń wá ọ̀nà láti rí irọ́? Sélà.   Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ìyàtọ̀ sí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀+ dájúdájú;Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbọ́ nígbà tí mo bá ké pè é.+   Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀.+Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín,+ lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Sélà.   Ẹ rú ẹbọ òdodo,+Kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+   Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń sọ pé: “Ta ni yóò fi oore hàn sí wa?”Gbé ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sókè sí wa lára,+ Jèhófà.   Dájúdájú, ìwọ yóò fún mi ní ayọ̀ yíyọ̀ nínú ọkàn-àyà mi+Ju ìgbà tí ọkà wọn àti wáìnì tuntun wọn pọ̀ gidigidi.+   Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn,+Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé