Sáàmù 39:1-13

Sí olùdarí Jédútúnì.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 39  Mo wí pé: “Ṣe ni èmi yóò máa ṣọ́ àwọn ọ̀nà mi+Láti má ṣe fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀.+Ṣe ni èmi yóò fi ìdínu tí ó rí bí ẹ̀ṣọ́ dí ẹnu mi,+Níwọ̀n ìgbà tí ẹni burúkú bá ti wà ní iwájú mi.”+  2  Mo fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ di aláìlèsọ̀rọ̀;+Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́ sí ohun rere,+Wíwà tí mo wà nínú ìrora ni a sì ta nù lẹ́gbẹ́.  3  Ọkàn-àyà mi gbóná nínú mi;+Nígbà ìmí ẹ̀dùn mi, iná ń jó.Mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀ pé:  4  “Jèhófà, jẹ́ kí n mọ òpin mi,+Àti ìwọ̀n ọjọ́ mi—ohun tí ó jẹ́,+Kí n lè mọ bí mo ti jẹ́ aláìwàpẹ́ tó.+  5  Wò ó! Ìwọ ti ṣe ọjọ́ mi ní kìkì ìwọ̀nba díẹ̀;+Gbogbo ọjọ́ ayé mi sì dà bí èyí tí kò tó nǹkan ní iwájú rẹ.+Dájúdájú, olúkúlùkù ará ayé, bí ó tilẹ̀ dúró gbọn-in gbọn-in, jẹ́ èémí àmíjáde lásán-làsàn.+ Sélà.  6  Dájúdájú, ní àwòrán ni ènìyàn ń rìn káàkiri.+Dájúdájú, lásán ni wọ́n jẹ́ aláriwo líle.+Ènìyàn ń to nǹkan jọ pelemọ, kò sì mọ ẹni tí yóò kó wọn.+  7  Wàyí o, kí ni mo ní ìrètí fún, Jèhófà?Ìfojúsọ́nà mi ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.+  8  Dá mi nídè nínú gbogbo ìrélànàkọjá mi.+Má ṣe gbé mi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀gàn fún òpònú.+  9  Mo ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ aláìlèsọ̀rọ̀;+ èmi kò lè la ẹnu mi,+Nítorí tí ìwọ fúnra rẹ gbé ìgbésẹ̀.+ 10  Mú ìyọnu rẹ kúrò lára mi.+Èmi ti wá sí òpin nítorí ìbánijà ọwọ́ rẹ.+ 11  Nípasẹ̀ àwọn ìbáwí àfitọ́nisọ́nà lórí ìṣìnà ni ìwọ ti tọ́ ènìyàn sọ́nà,+Ìwọ sì jẹ àwọn ohun tí ó ní ìfẹ́-ọkàn sí run gẹ́gẹ́ bí òólá+ ti ń ṣe.Dájúdájú, olúkúlùkù ará ayé jẹ́ èémí àmíjáde.+ Sélà. 12  Gbọ́ àdúrà mi, Jèhófà,Sì fi etí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+Má ṣe dákẹ́ sí omijé mi.+Nítorí pé àtìpó lásán ni mo jẹ́ lọ́dọ̀ rẹ,+Olùtẹ̀dó bákan náà bí gbogbo baba ńlá mi.+ 13  Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, kí n lè túra ká+Kí èmi tó lọ láìsí mọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé