Sáàmù 35:1-28

Ti Dáfídì. 35  Jèhófà, bá mi dá ẹjọ́ mi lòdì sí àwọn tí ó kọjú ìjà sí mi;+Àwọn tí ń bá mi jagun ni kí o bá jagun.+   Di asà àti apata ńlá mú,+Kí o sì dìde fún ìrànwọ́ mi,+   Sì fa ọ̀kọ̀ àti àáké abẹnuméjì yọ láti fi pàdé àwọn tí ń lépa mi.+Wí fún ọkàn mi pé: “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”+   Kí ìtìjú bá àwọn tí ń dọdẹ ọkàn mi, kí a sì tẹ́ wọn lógo.+Kí a dá àwọn tí ń pète-pèrò ìyọnu àjálù fún mi padà, kí wọ́n sì tẹ́.+   Kí wọ́n dà bí ìyàngbò níwájú ẹ̀fúùfù,+Kí áńgẹ́lì Jèhófà sì máa tì wọ́n lọ.+   Kí ọ̀nà wọ́n di òkùnkùn àti àwọn ibi yíyọ̀bọ̀rọ́,+Kí áńgẹ́lì Jèhófà sì máa lépa wọn.   Nítorí pé láìnídìí ni wọ́n fi kòtò aláwọ̀n tí í ṣe tiwọn pa mọ́ dè mí;+Láìnídìí ni wọ́n gbẹ́ ẹ fún ọkàn mi.+   Kí ìparun wá sórí rẹ̀ láìjẹ́ pé ó mọ̀,+Kí àwọ̀n òun fúnra rẹ̀ tí ó fi pa mọ́ sì mú un;+Pẹ̀lú ìparun ni kí ó já sínú rẹ̀.+   Ṣùgbọ́n kí ọkàn mi kún fún ìdùnnú nínú Jèhófà;+Kí ó máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú ìgbàlà rẹ̀.+ 10  Kí gbogbo egungun mi wí pé:+“Jèhófà, ta ni ó dà bí rẹ,+Tí ń dá ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nídè lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù ú lọ,+Àti ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì lọ́wọ́ ẹni tí ń jà á lólè?”+ 11  Àwọn ẹlẹ́rìí tí ń ṣeni léṣe dìde;+Ohun tí n kò mọ̀ ni wọ́n ń bi mí.+ 12  Wọ́n ń fi búburú san rere fún mi,+Ọ̀fọ̀ fún ọkàn mi.+ 13  Ní tèmi, nígbà tí wọ́n ń ṣàmódi, aṣọ àpò ìdọ̀họ ni aṣọ mi,+Mo fi ààwẹ̀ gbígbà ṣẹ́ ọkàn mi níṣẹ̀ẹ́,+Àdúrà mi a sì padà sí oókan àyà mi.+ 14  Ní ti alábàákẹ́gbẹ́, ní ti arákùnrin tèmi,+Mo ń rìn káàkiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyá.+Nínú ìbànújẹ́, mo tẹrí ba. 15  Ṣùgbọ́n nígbà tí mo ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́, ṣe ni wọ́n ń yọ̀, tí wọ́n sì kóra jọpọ̀;+Wọ́n kóra jọpọ̀ lòdì sí mi,+Wọ́n ṣá mi balẹ̀ nígbà tí n kò mọ̀;+Wọ́n fà mí ya sí wẹ́wẹ́, wọn kò sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.+ 16  Láàárín àwọn apẹ̀yìndà afiniṣẹlẹ́yà nítorí àkàrà+Wíwa eyín wọn pọ̀ ń bẹ àní sí mi.+ 17  Jèhófà, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa wò ó?+Mú ọkàn mi padà wá kúrò nínú ìpanirun wọn,+Àní ọ̀kan ṣoṣo tèmi+ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀. 18  Ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá;+Èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye.+ 19  Kí àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìsí ìdí má yọ̀ mí;+Ní ti àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí, má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́jú.+ 20  Nítorí pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ àlàáfíà ni wọ́n ń sọ;+Ṣùgbọ́n sí àwọn ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ilẹ̀ ayé,Àwọn ohun ẹ̀tàn ní wọ́n ń pète-pèrò ṣáá.+ 21  Wọ́n sì la ẹnu wọn gbàù, àní sí mi.+Wọ́n wí pé: “Àháà! Àháà! ojú wa ti rí i.”+ 22  Ìwọ ti rí i, Jèhófà.+ Má ṣe dákẹ́.+Jèhófà, má jìnnà réré sí mi.+ 23  Ru ara rẹ dìde, kí o sì jí sí ìdájọ́ mi,+Ìwọ Ọlọ́run mi, àní Jèhófà, sí ẹjọ́ mi lábẹ́ òfin.+ 24  Ṣe ìdájọ́ mi gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi,+Kí wọ́n má sì yọ̀ mí.+ 25  Kí wọ́n má sọ ní ọkàn-àyà wọn pé: “Àháà, ọkàn wa!”+Kí wọ́n má sọ pé: “Àwa ti gbé e mì.”+ 26  Kí ojú tì wọ́n, kí gbogbo wọn sì tẹ́ lápapọ̀+Àwọn tí ó kún fún ìdùnnú sí ìyọnu àjálù mi.+Kí a da aṣọ ìtìjú+ àti ìtẹ́lógo bo àwọn tí ń gbé àgbéré ńláǹlà sí mi.+ 27  Kí wọ́n fi ìdùnnú ké jáde, kí wọ́n sì máa yọ̀, àwọn tí ó ní inú dídùn sí òdodo mi.+Kí wọ́n sì máa wí nígbà gbogbo pé:+“Kí Jèhófà di àgbégalọ́lá, ẹni tí ó ní inú dídùn sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”+ 28  Kí ahọ́n mi sì máa sọ òdodo rẹ jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,+Ìyìn rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé