Sáàmù 33:1-22
33 Ẹ fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olódodo, nítorí Jèhófà.+Ìyìn yẹ níhà ọ̀dọ̀ àwọn adúróṣánṣán.+
2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà lórí háàpù;+Ẹ kọ orin atunilára sí i lórí ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá.+
3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;+Ẹ sa gbogbo ipá yín ní títa àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ti ẹ̀yin ti igbe ìdùnnú.+
4 Nítorí tí ọ̀rọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán,+Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ nínú ìṣòtítọ́.+
5 Òun jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.+Ilẹ̀ ayé kún fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà.+
6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ṣe ọ̀run,+Nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ sì ni a ṣe gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.+
7 Ó gbá omi òkun jọ bí ẹni pé nípasẹ̀ ìsédò,+Ó fi omi ríru sínú àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́.
8 Kí gbogbo ará ilẹ̀ ayé bẹ̀rù Jèhófà.+Kí jìnnìjìnnì bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso nítorí rẹ̀.+
9 Nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì wá wà;+Òun fúnra rẹ̀ pàṣẹ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dúró bẹ́ẹ̀.+
10 Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fọ́ ète àwọn orílẹ̀-èdè túútúú;+Ó ti ké ìrònú àwọn ènìyàn nígbèrí.+
11 Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró;+Ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ ń bẹ láti ìran kan tẹ̀ lé ìran mìíràn.+
12 Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀,+Àwọn ènìyàn tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀.+
13 Jèhófà wò láti ọ̀run,+Ó rí gbogbo ọmọ ènìyàn.+
14 Láti ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀ tí ó ń gbé+Ó tẹjú mọ́ gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé.
15 Ó ṣẹ̀dá ọkàn-àyà wọn lápapọ̀;+Ó ń gbé gbogbo iṣẹ́ wọn yẹ̀ wò.+
16 Kò sí ọba kankan tí a gbà là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹgbẹ́ ológun;+Alágbára ńlá ènìyàn ni a kò dá nídè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ yanturu agbára.+
17 Ẹṣin jẹ́ ẹ̀tàn fún ìgbàlà,+Kò sì lè pèsè àsálà nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ yanturu ìmí rẹ̀.+
18 Wò ó! Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+Lọ́dọ̀ àwọn tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́,+
19 Láti dá ọkàn wọn nídè lọ́wọ́ ikú pàápàá,+Àti láti pa wọ́n mọ́ láàyè ní àkókò ìyàn.+
20 Àní ọkàn wa ti ń fojú sọ́nà fún Jèhófà.+Òun ni olùrànlọ́wọ́ wa àti apata wa.+
21 Nítorí tí ọkàn-àyà wa ń yọ̀ nínú rẹ̀;+Nítorí tí a gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.+
22 Jèhófà, kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ wà lára wa,+Àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń dúró dè ọ́.+

