Sáàmù 32:1-11
Ti Dáfídì. Másíkílì.
32 Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.+
2 Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn,+Ẹni tí ẹ̀tàn kò sì sí nínú ẹ̀mí rẹ̀.+
3 Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+
4 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni ọwọ́ rẹ wúwo lára mi.+Ọ̀rinrin ìgbésí ayé mi ni a ti yí padà bí ti àkókò ooru gbígbẹ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.+ Sélà.
5 Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀.+Mo wí pé: “Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.”+Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.+ Sélà.
6 Ní tìtorí èyí, gbogbo ẹni ìdúróṣinṣin yóò máa gbàdúrà sí ọ+Ní kìkì irúfẹ́ àkókò tí a lè rí ọ.+Ní ti àkúnya ọ̀pọ̀ omi, wọn kì yóò kàn án lára.+
7 Ibi ìlùmọ́ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ mi kúrò nínú wàhálà pàápàá.+Ìwọ yóò fi igbe ìdùnnú yí mi ká lẹ́nu pípèsè àsálà.+ Sélà.
8 “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀.+Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.+
9 Ẹ má sọ ara yín di ẹṣin tàbí ìbaaka tí kò ní òye,+Tí ó jẹ́ pé ìjánu tàbí okùn ẹran ni a fi ń ki ìtapọ́n-ún-pọ́n-ún rẹ̀ wọ̀+Kí ó tó di pé wọn yóò sún mọ́ ọ.”+
10 Ọ̀pọ̀ ni ìrora tí ẹni burúkú ní;+Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni ó yí i ká.+
11 Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú, ẹ̀yin olódodo;+Kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo ẹ̀yin adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.+

