Sáàmù 31:1-24
Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì.
31 Ìwọ, Jèhófà, ni mo sá di.+Kí ojú má tì mí láé.+Nínú òdodo rẹ, pèsè àsálà fún mi.+
2 Dẹ etí sí mi.+Dá mi nídè kánkán.+Di ibi odi agbára tí a fi òkúta ṣe fún mi,+Ilé àwọn ibi odi agbára láti gbà mí là.+
3 Nítorí ìwọ ni àpáta gàǹgà mi àti ibi odi agbára mi;+Àti nítorí orúkọ rẹ,+ ìwọ yóò ṣamọ̀nà mi, ìwọ yóò sì darí mi.+
4 Ìwọ yóò yọ mí jáde nínú àwọ̀n tí wọ́n fi pa mọ́ dè mí,+Nítorí pé ìwọ ni odi agbára mi.+
5 Ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.+Ìwọ ti tún mi rà padà,+ Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.+
6 Èmi kórìíra àwọn tí ń fiyè sí àwọn òrìṣà asán, tí kò ní láárí;+Ṣùgbọ́n ní tèmi, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+
7 Dájúdájú, èmi yóò kún fún ìdùnnú, èmi yóò sì máa yọ̀ nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+Ní ti pé ìwọ ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́;+Ìwọ ti mọ̀ nípa àwọn wàhálà ọkàn mi,+
8 Ìwọ kò sì fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́.+Ìwọ ti mú kí ẹsẹ̀ mi dúró ní ibi tí ó ní àyè gbígbòòrò.+
9 Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà, nítorí pé mo wà nínú hílàhílo.+Ìbìnújẹ́ ti sọ ojú mi di aláìlera,+ ọkàn mi àti ikùn mi.+
10 Nítorí pé ẹ̀dùn-ọkàn ti mú ìgbésí ayé mi wá sí òpin,+Àti àwọn ọdún mi nínú ìmí ẹ̀dùn.+Nítorí ìṣìnà mi, agbára mi ti kọsẹ̀,+Àní egungun mi ti di aláìlera.+
11 Lójú ìwòye gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi,+ mo ti di ẹni ẹ̀gàn,+Mo sì ti dà bẹ́ẹ̀ gan-an sí àwọn aládùúgbò mi,+Mo sì ti di ẹni tí ń fa ìbẹ̀rùbojo sí àwọn ojúlùmọ̀ mi.+Nígbà tí wọ́n rí mi lóde, wọ́n sá fún mi.+
12 Bí ẹni tí ó ti kú, tí kò sì sí nínú ọkàn-àyà, mo ti di ẹni ìgbàgbé;+Mo dà bí ohun èlò tí ó bàjẹ́;+
13 Nítorí mo ti gbọ́ ìròyìn búburú lẹ́nu ọ̀pọ̀ ènìyàn,+Jìnnìjìnnì ń bẹ ní ìhà gbogbo.+Nígbà tí wọ́n wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí mi,+Láti gba ọkàn mi kúrò ni wọ́n ṣe ń pète-pèrò.+
14 Ṣùgbọ́n èmi—ìwọ Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+Mo ti wí pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.”+
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.+Dá mi nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti kúrò ní ọwọ́ àwọn tí ń lépa mi.+
16 Mú kí ojú rẹ tàn sára ìránṣẹ́ rẹ.+Gbà mí là nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+
17 Jèhófà, kí ojú má tì mí, nítorí pé mo ti ké pè ọ́.+Kí ojú ti àwọn ẹni burúkú;+Kí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ nínú Ṣìọ́ọ̀lù.+
18 Kí ètè èké di aláìlèsọ̀rọ̀,+Èyí tí ń sọ̀rọ̀ láìníjàánu nínú ìrera àti ìfojú-tín-ín-rín+ lòdì sí olódodo.+
19 Oore rẹ mà pọ̀ yanturu o,+ èyí tí o ti tò pa mọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ!+Èyí tí o ti ṣe fún àwọn tí ó sá di ọ́,Ní iwájú àwọn ọmọ ènìyàn.+
20 Ìwọ yóò fi wọ́n pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ ìwọ alára+Kúrò nínú ìpàdípọ̀ àwọn ènìyàn.+Ìwọ yóò fi wọ́n pa mọ́ sínú àtíbàbà rẹ kúrò nínú aáwọ̀ ahọ́n.+
21 Ìbùkún ni fún Jèhófà,+Nítorí ó ti ṣe àgbàyanu inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí mi nínú ìlú ńlá tí ó wà lábẹ́ másùnmáwo.+
22 Ní tèmi, mo wí nígbà tí ẹ̀rù jìnnìjìnnì bò mí pé:+“Dájúdájú, a ó pa mí run pátápátá kúrò ní iwájú rẹ.”+Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohùn ìpàrọwà mi nígbà tí mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́.+
23 Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn olùṣòtítọ́,+Ṣùgbọ́n ó ń san ẹ̀san lọ́nà tí ó peléke fún ẹnikẹ́ni tí ń hùwà ìrera.+
24 Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ọkàn-àyà yín sì jẹ́ alágbára,+Gbogbo ẹ̀yin tí ń dúró de Jèhófà.+

