Sáàmù 29:1-11
Orin atunilára ti Dáfídì.
29 Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ọmọ àwọn alágbára,Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.+
2 Ẹ gbé ògo tí ó yẹ orúkọ Jèhófà fún un.+Ẹ tẹrí ba fún Jèhófà nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́.+
3 Ohùn Jèhófà ń bẹ lórí omi;+Ọlọ́run ògo+ ti sán ààrá.+Jèhófà ń bẹ lórí omi púpọ̀.+
4 Ohùn Jèhófà lágbára;+Ohùn Jèhófà jẹ́ ọlọ́lá ńlá.+
5 Ohùn Jèhófà ń fa àwọn kédárì ya;Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń fa àwọn kédárì Lẹ́bánónì ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,+
6 Ó sì ń mú kí wọ́n máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí ọmọ màlúù,+Lẹ́bánónì àti Síríónì+ ń ṣe bí ọmọ akọ màlúù ìgbẹ́.
7 Ohùn Jèhófà ń fi ọwọ́ iná gé nǹkan;+
8 Àní ohùn Jèhófà ń mú kí aginjù jà ràpà,+Jèhófà ń mú kí aginjù Kádéṣì+ jà ràpà.
9 Àní ohùn Jèhófà ń mú kí àwọn egbin jà ràpà nínú ìrora ìbímọ,+Ó sì ń tú àwọn igbó sí borokoto.+Nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń wí pé: “Ògo!”+
10 Jèhófà ti jókòó sórí àkúnya omi;+Jèhófà sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
11 Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi okun fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní tòótọ́.+Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi àlàáfíà bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀.+

