Sáàmù 28:1-9

Ti Dáfídì. 28  Ìwọ, Jèhófà, ni mo ń pè ṣáá.+Ìwọ Àpáta mi, má dití sí mi,+Kí o má bàa dákẹ́ jẹ́ẹ́ sí mi+Kí n má sì wá dà bí àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+   Gbọ́ ohùn ìpàrọwà mi nígbà tí mo bá kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́,Nígbà tí mo bá gbé ọwọ́+ mi sókè sí yàrá inú pátápátá ibi mímọ́ rẹ.+   Má ṣe kó mi pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn aṣenilọ́ṣẹ́,+Àwọn tí ń bá àwọn alábàákẹ́gbẹ́+ wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ohun búburú ni ó wà nínú ọkàn-àyà wọn.+   Fi fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ wọn+Àti gẹ́gẹ́ bí búburú ìṣe wọn.+Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni kí o fi fún wọn.+San ìgbòkègbodò iṣẹ́ wọn padà fún wọn.+   Nítorí tí wọn kò ka àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà sí rárá,+Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí.+Òun yóò ya wọ́n lulẹ̀, kì yóò sì gbé wọn ró.   Ìbùkún ni fún Jèhófà, nítorí tí ó ti gbọ́ ohùn ìpàrọwà mi.+   Jèhófà ni okun mi+ àti apata mi.+Òun ni ọkàn-àyà mi gbẹ́kẹ̀ lé,+A sì ti ràn mí lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà mi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà,+Èmi yóò sì fi orin mi gbé e lárugẹ.+   Jèhófà jẹ́ okun fún àwọn ènìyàn rẹ̀,+Òun sì jẹ́ ibi odi agbára ti ìgbàlà títóbi lọ́lá fún ẹni àmì òróró rẹ̀.+   Gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bù kún ogún rẹ;+Kí o sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, kí o sì máa gbé wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé