Sáàmù 25:1-22
Ti Dáfídì.
א [Áléfì]
25 Jèhófà, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbé ọkàn mi gan-an sókè sí.+
ב [Bétì]
2 Ìwọ Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+Kí ojú má ṣe tì mí.Kí àwọn ọ̀tá mi má yọ ayọ̀ ńláǹlà lé mi lórí.+
ג [Gímélì]
3 Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹnì kankan tí ojú yóò tì lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ.+Àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè láìkẹ́sẹ járí ni ojú yóò tì.+
ד [Dálétì]
4 Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà;+Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.+
ה [Híì]
5 Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi,+Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.+
ו [Wọ́ọ̀]Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+
ז [Sáyínì]
6 Rántí àwọn àánú rẹ,+ Jèhófà, àti àwọn inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+Nítorí tí wọ́n wà láti àkókò tí ó lọ kánrin.+
ח [Kétì]
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi àti àwọn ìdìtẹ̀ mi.+Gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni kí ìwọ rántí mi,+Nítorí oore rẹ, Jèhófà.+
ט [Tétì]
8 Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà.+Ìdí nìyẹn tí ó fi ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà náà.+
י [Yódì]
9 Òun yóò mú kí àwọn ọlọ́kàn tútù máa rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀,+Yóò sì kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.+
כ [Káfì]
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Jèhófà jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́Fún àwọn tí ń pa májẹ̀mú+ rẹ̀ àti àwọn ìránnilétí+ rẹ̀ mọ́.
ל [Lámédì]
11 Nítorí orúkọ rẹ, Jèhófà,+Àní kí o dárí ìṣìnà mi jì, nítorí tí ó pọ̀ níye.+
מ [Mémì]
12 Wàyí o, ta ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà?+Òun yóò fún un ní ìtọ́ni ní ọ̀nà tí yóò yàn.+
נ [Núnì]
13 Ọkàn rẹ̀ yóò máa gbé nínú ohun rere,+Ọmọ rẹ̀ yóò sì gba ilẹ̀ ayé.+
ס [Sámékì]
14 Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+Àti májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú, láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.+
ע [Áyínì]
15 Ojú mi ń bẹ lọ́dọ̀ Jèhófà nígbà gbogbo,+Nítorí pé òun ni ó fa ẹsẹ̀ mi yọ kúrò nínú àwọ̀n.+
פ [Péè]
16 Yí ojú rẹ sọ́dọ̀ mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi;+Nítorí tí mo dá nìkan wà, a sì ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.+
צ [Sádì]
17 Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀;+Mú mi jáde kúrò nínú másùnmáwo tí ó bá mi.+
ר [Réṣì]
18 Wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́ àti ìdààmú mi,+Kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.+
19 Wo bí àwọn ọ̀tá mi ti pọ̀ tó,+Ìkórìíra lílenípá sì ni wọ́n fi kórìíra mi.+
ש [Ṣínì]
20 Ṣọ́ ọkàn mi, kí o sì dá mi nídè.+Kí ojú má ṣe tì mí, nítorí pé mo ti sá di ọ́.+
ת [Tọ́ọ̀]
21 Jẹ́ kí ìwà títọ́ àti ìdúróṣánṣán pàápàá máa fi ìṣọ́ ṣọ́ mi,+Nítorí tí mo ti ní ìrètí nínú rẹ.+
22 Ọlọ́run, tún Ísírẹ́lì rà padà kúrò nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.+

