Sáàmù 23:1-6
Orin atunilára ti Dáfídì.
23 Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.+Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.+
2 Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko;+Ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa.+
3 Ó ń tu ọkàn mi lára.+Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.+
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji,+Èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan,+Nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi;+Ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.+
5 Ìwọ ṣètò tábìlì síwájú mi ní iwájú àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi.+Ìwọ fi òróró pa orí mi;+Ife mi kún dáadáa.+
6 Dájúdájú, ohun rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;+Èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà fún gígùn ọjọ́.+

