Sáàmù 22:1-31
Sí olùdarí lórí Egbin Ọ̀yẹ̀. Orin atunilára ti Dáfídì.
22 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi fi mí sílẹ̀?+Èé ṣe tí ìwọ fi jìnnà sí gbígbà mí là,+Sí àwọn ọ̀rọ̀ ìkéramúramù mi?+
2 Ìwọ Ọlọ́run mi, mo ń pè ṣáá ní ọ̀sán, ìwọ kò sì dáhùn;+Àti ní òru, ìdákẹ́jẹ́ẹ́ kò sì sí níhà ọ̀dọ̀ mi.+
3 Ṣùgbọ́n mímọ́ ni ìwọ,+Tí ń gbé nínú ìyìn Ísírẹ́lì.+
4 Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀ lé;+Wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì ń bá a nìṣó ní pípèsè àsálà fún wọn.+
5 Ìwọ ni wọ́n kígbe pè,+ wọ́n sì yè bọ́;+Ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé, ìtìjú kò sì bá wọn.+
6 Ṣùgbọ́n kòkòrò mùkúlú ni mí,+ èmi kì í sì í ṣe ènìyàn,Ẹni ẹ̀gàn fún àwọn ènìyàn àti ẹni ìtẹ́ńbẹ́lú fún àwọn ènìyàn.+
7 Ní ti gbogbo àwọn tí ń rí mi, wọ́n ń fi mí ṣẹ̀sín;+Wọ́n ń la ẹnu wọn gbàùgbàù, wọ́n ń mi orí wọn pé:+
8 “Ó fi ara rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́.+ Kí Ó pèsè àsálà fún un!+Kí ó dá a nídè, níwọ̀n bí ó ti ní inú dídùn sí i!”+
9 Nítorí pé ìwọ ni Ẹni tí ó fà mí jáde láti inú ikùn,+Ẹni tí ó mú kí n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nígbà tí mo wà lẹ́nu ọmú ìyá mi.+
10 Ìwọ ni a gbé mi lé lọ́wọ́ láti inú ilé ọlẹ̀;+Ìwọ ni Ọlọ́run mi láti inú ikùn ìyá mi wá.+
11 Má jìnnà réré sí mi, nítorí pé wàhálà ń bẹ nítòsí,+Nítorí pé kò sí olùrànlọ́wọ́ mìíràn.+
12 Ọ̀pọ̀ ẹgbọrọ akọ màlúù ti yí mi ká;+Àwọn alágbára Báṣánì pàápàá ti rọ̀gbà yí mi ká.+
13 Wọ́n ti la ẹnu wọn sí mi,+Bí kìnnìún tí ń fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì ń ké ramúramù.+
14 A ti tú mi jáde bí omi,+A sì ti ya gbogbo egungun mi sọ́tọ̀ sí ara wọn.+Ọkàn-àyà mi ti dà bí ìda;+Ó ti yọ́ jinlẹ̀-jinlẹ̀ ní ìhà inú mi.+
15 Agbára mi ti gbẹ gẹ́gẹ́ bí àpáàdì,+A sì mú kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ ẹran ìdí eyín mi;+Ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ sínú ekuru ikú.+
16 Nítorí pé àwọn ajá ti yí mi ká;+Àpéjọ àwọn aṣebi pàápàá ti ká mi mọ́.+Bí kìnnìún, wọ́n wà níbi ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi.+
17 Mo lè ka iye gbogbo egungun mi.+Àní wọ́n ń wò, wọ́n tẹjú mọ́ mi.+
18 Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn,+Wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ mi.+
19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà, má jìnnà réré.+Ìwọ okun+ mi, ṣe kánkán láti wá ṣe ìrànwọ́ fún mi.+
20 Dá ọkàn mi nídè kúrò lọ́wọ́ idà,+Ọ̀kan ṣoṣo tí ó jẹ́ tèmi kúrò ní àtẹ́sẹ̀ ajá;+
21 Gbà mí là kúrò ní ẹnu kìnnìún,+Dá mi lóhùn, kí o sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù ìgbẹ́.+
22 Ṣe ni èmi yóò máa polongo orúkọ+ rẹ fún àwọn arákùnrin mi;+Èmi yóò máa yìn ọ́ ní àárín ìjọ.+
23 Ẹ̀yin olùbẹ̀rù Jèhófà, ẹ yìn ín!+Gbogbo ẹ̀yin irú-ọmọ Jékọ́bù, ẹ yìn ín lógo!+Kí jìnnìjìnnì sì bá yín nítorí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin irú-ọmọ Ísírẹ́lì.+
24 Nítorí tí òun kò tẹ́ńbẹ́lú+Bẹ́ẹ̀ ni kò kórìíra ìṣẹ́ ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́;+Kò sì fi ojú pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,+Nígbà tí ó sì kígbe pè é fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́.+
25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ìyìn mi yóò wà ní ìjọ ńlá;+Èmi yóò san àwọn ẹ̀jẹ́ mi ní iwájú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+
26 Àwọn ọlọ́kàn tútù yóò jẹ, wọn yóò sì yó;+Àwọn tí ń wá a yóò yin Jèhófà.+Kí ọkàn-àyà yín wà láàyè títí láé.+
27 Gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rántí, yóò sì yí padà sọ́dọ̀ Jèhófà.+Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹrí ba níwájú rẹ.+
28 Nítorí pé ti Jèhófà ni ipò ọba,+Ó sì ń jọba lé àwọn orílẹ̀-èdè lórí.+
29 Gbogbo àwọn tí ó sanra ní ilẹ̀ ayé yóò jẹ, wọn yóò sì tẹrí ba;+Gbogbo àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ekuru yóò tẹ̀ ba níwájú rẹ̀,+Kò sì sí ẹnì kankan tí yóò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ láàyè.+
30 Àní irú-ọmọ kan yóò máa sìn ín;+A ó polongo rẹ̀ nípa Jèhófà fún ìran náà.+
31 Wọn yóò wá, wọn yóò sì sọ nípa òdodo rẹ̀+Fún àwọn ènìyàn tí a óò bí, pé òun ni ó ṣe èyí.+

